Nigeria virtual courtroom: Ìjọba Naijiria ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò ìgbẹ́jọ́ lórí ayélujára

Ileeṣẹ ijọba apapọ fun eto idajọ, ti ṣe ifilọlẹ eto tuntun kan ti yoo mu ko ṣeeṣe fun awọn ile ẹjọ lati ma a ṣe igbẹjọ lori ayelujara.
Ijọba sọ pe eto tuntun naa yoo mu adinku ba bi awọn eeyan ṣe n pọju ninu ọgba ẹwọn, ti yoo si tun daabo bo awọn ẹlẹwọn ati awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn kuro lọwọ aarun Coronavirus.
Minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami, lo ṣe ifilọlẹ eto naa ni ọgba ẹwọn Kuje, to wa niluu Abuja.
- Àwọn mọ̀lẹ́bí Sylvester Oromoni bẹ Femi Falana lọ́wẹ̀ láti pe Dowen College lẹ́jọ́
- A ṣetán láti bá Sanwo-Olu rìnrìn àlàáfíà, ẹ̀yin krìstẹ́nì, ẹ darapọ̀ mọ wa- MURIC
- Fásitì fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún olùkọ́ tó nawọ́ eré ìfẹ́ sí akẹ́kọ̀ọ́
- Ní kíákíá ẹ yí ìpinnu yín padà sí Nàìjíríà lórí ẹda ààrùn COVID-19 Omicron-Lai Mohammed
Oluranlọwọ pataki fun minisita naa lori eto iroyin, Ọmọwe Umar Jibrilu Gwandu, sọ pe eto tuntun naa yoo tun fi opin si idaduro to ma n mu ki awọn ẹjọ o falẹ kaakiri Naijiria.
"Bakan naa ni eto naa yoo tun mu adinku ba gbigbe awọn afurasi ọdaran lati ọgba ẹwọn lọ si ile ẹjọ, to fi mọ agbẹjọro wọn ati awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn.
Ọmọwe Jibrilu sọ pe eto tuntun naa ko tako ofin Naijiria rara.
O ni o wa ni ibamu pẹlu abala kẹrindinlogoji, ẹsẹ kẹta ofin Naijiria pe ni gbangba ni ki gbogbo igbẹjọ ti ma a waye, lai si aṣiri ikọkọ kankan.
Agbẹjọro kan to ba BBC sọrọ, Aisha Isa sọ pe eto tuntun yii yoo fi opin si awọn idiwọ ati iṣoro ti awọn ma n koju lasiko igbẹjọ, ti ko si ni mu ki ẹjọ o falẹ mọ.
Bakan naa ni Minisita fun ọrọ abẹle, Rauf Aregbesola, sọ pe eto tuntun yii yoo din inawo ijọba ku lori lilọ bibọ awọn ẹlẹwọn lọ si ile ẹjọ, to fi mọ awọn ewu to rọ mọ igbokegbodo ọhun.













