KWASU: Fásitì fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún olùkọ́ tó nawọ́ eré ìfẹ́ sí akẹ́kọ̀ọ́

Oríṣun àwòrán, other
Awọn alaṣẹ ile ẹkọ fasiti ipinlẹ Kwara ti gba iṣẹ lọwọ olukọ kan Pelumi Adewale lori ẹsun pe o n fi Ibalopọ halẹ mọ akẹkọọ kan Tosin Adegunsoye.
Oga àgbà fasiti naa Mustapha Akanbi, lo tu kẹkẹ ọrọ yi si'ta lasiko to n ba akọroyin sọrọ saaju ayẹyẹ ikẹkọ jade fasiti naa to de tan.
Akanbi ni Adewale ko ti jẹ oṣiṣẹ fasiti naa mọ pẹlu iwa to tabuku orukọ fasiti naa.
- 'Ọmọ mi mẹ́rin, ọmọ àbúrò mi mẹ́ta ló wà lára àwọn ọmọ tí wọ́n bá òkú wọ́n nínú ọkọ̀'
- Ní kíákíá ẹ yí ìpinnu yín padà sí Nàìjíríà lórí ẹda ààrùn COVID-19 Omicron-Lai Mohammed
- BBC kéde àwọn tó pegedé láti gba àmì ẹ̀yẹ èrè ìdárayá ọdún 2021
- Ìdí tí mo fi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọmọ mi lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tó dágbére fáyé rèé - Bàbá Sylvester Oromoni
"Awon agbofinro ti toju bọ ọrọ yi koda o ti wa nile ẹjọ ba se n sọrọ yi.Amo mo fi n da yin loju pe arakunrin naa kii se oṣiṣẹ wa mọ.Awa kii faaye gba iru iwà bayii."
Gẹgẹ bi ileesẹ iroyin NAN ti ṣe jabọ, ọjọ Kọkànlá osu Kẹsan ni wọn gbe arakunrin ọhun lọ siwaju adajọ majisreeti lori ẹsun pe o n fi Ibalopọ lọ eeyan lọnà tí kò tọ.
Ẹka ọtẹlẹmuyẹ nipinlẹ naa lo gbe lo s'ile ẹjọ lori ẹsun ifipabanilopo ati makaruru lasiko idanwo.
Iroyin to wa ninu iwe ipẹjọ fi hàn pé lọjọ kẹẹdogun oṣù Kẹwàá ni Adegunsoye fesun kan ọgbẹni Adewale to n kọ lẹkọ imọ Biology pe o kesi tó sì balẹ pé bi ko ba je kí oun baa lajọsepọ yóò fidi rẹmi ninu idanwo.









