Badagry children death: Mẹ́rin nínú àwọn ọmọ mẹ́jọ tó kú ní Badagry ni wọ́n jẹ́ ọmọ baba kan náà

Ọgbẹni Ibrahim Sebrila sọ fun BBC pe mẹrin ni ọmọ lara awọn ọmọ naa, ti aburo rẹ ọkunrin si ni mẹta.

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Ibrahim Sebrila sọ fun BBC pe mẹrin ni ọmọ lara awọn ọmọ naa, ti aburo rẹ ọkunrin si ni mẹta.

Awọn obi awọn ọmọde mẹjọ to ku sinu ọkọ ayọkẹlẹ kan ni ilu Badagry nipinlẹ Eko ti ba BBC Yoruba sọrọ.

Alaga ijọba ibilẹ Olorunda, nibi ti awọn ọmọde mẹjọ kan ti padanu ẹmi wọn sinu ọkọ kan, Samson Olatunde sọ pe ile awọn ọmọ naa wa lẹgbẹ ara wọn ni.

Gẹgẹ bi ohun to tẹ BBC News Yoruba lọwọ ṣe sọ, mẹrin ninu awọn ọmọ to jalaisi naa ni wọn wa lati ile kan naa, ti mẹta si wa lati ile miran.

Gẹgẹ bi nkan to sọ fun aṣojukọroyin BBC, Ọgbẹni Olatunde sọ pe iya arugbo kan lo n gbe inu ile ti wọn ti ba oku awọn ọmọ ọhun ninu ọkọ, to si ni ṣọọbu si iwaju ita.

O ni bẹẹni ko si ẹni to le sọ bi awọn ọmọ naa ṣe wọ inu ọgba ile ọhun, botilẹ jẹ pe ẹgbẹ ile wọn lo wa.

Inu ọgba ile yii ni wọn ti ba oku awọ̀n ọmọ naa. Ṣugbọn awọn ọlọpaa ti ti ilẹkun rẹ pa bayii.

Oríṣun àwòrán, Sceenshot

Àkọlé àwòrán, Inu ọgba ile yii ni wọn ti ba oku awọ̀n ọmọ naa. Ṣugbọn awọn ọlọpaa ti ti ilẹkun rẹ pa bayii.

Iya arugbo naa lo ri awọn ọmọ naa, to si pe iya ẹnikan lara wọn pe ko wa a wo awọn ọmọ wọn ninu ọkọ ayọkẹlẹ Honda Pilot ọhun.

A gbọ pe o ti to ọdun diẹ ti wọn ti gbe ọkọ ayọkẹlẹ naa sinu ọgba ile naa.

"Iya awọn ọmọ naa sare lọ sibi ti ọkọ naa wa, ṣugbọn ko si kọkọrọ lẹnu ilẹkun ọkọ. Lẹyin naa ni ọmọkunrin kan jade lati ile to dojukọ ile naa, o wọ inu palọ ile, o si mu kọkọrọ ọkọ naa jade.

"Ni kete to ṣi ilẹkun ọkọ naa, ti wọn ko oku awọn ọmọ ọhun jade ni ẹnikẹni ko mọ bo ṣe salọ."

Meje ni awọn ọmọ to kọkọ ku, ọkan lara awọn ọmọ naa to jẹ ikẹjọ ni wọn ba laaye, ṣugbọn o ku ki wọn o to gbe de ileewosan.

Ọmọ-ọmọ iya arugbo naa ni wọn pe e.

Iroyin sọ pe awọn ọlọpaa ti mu iya arugbo naa lọ si agọ wọn, ti wọn si tun mu arakunrin kan to pada wọ inu ọgba ile ọhun lati ti ilẹkun ọkọ lẹyin wakati diẹ ti wọn ṣawari oku awọn ọmọ naa.

Bakan naa la gbọ pe ẹya Hausa ni obi awọn ọmọ ọhun.

Bakan naa ni ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa, Ọgbẹni Ibrahim Sebrila sọ fun BBC pe oun loun bi mẹrin lara awọn ọmọ naa, ti aburo rẹ ọkunrin si ni mẹta.

Ọgbẹni Ibrahim Sebrila sọ fun BBC pe mẹrin ni ọmọ lara awọn ọmọ naa, ti aburo rẹ ọkunrin si ni mẹta.

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Ibrahim Sebrila sọ fun BBC pe mẹrin ni ọmọ lara awọn ọmọ naa, ti aburo rẹ ọkunrin si ni mẹta.

O sọ pe ọdun meji sẹyin ni ẹni to ni ọkọ naa ku.

Ko si ẹni to tii le sọ bi ilẹkun ọkọ naa ṣe ti pa mọ wọn, boya wọn tẹ bọtini to ma n ti gbogbo ilẹkun ọkọ ni.

Awọn obi awọn ọmọ naa to ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe mọṣalaaṣi kan to wa ni adugbo naa ni awọn ọmọ naa ti n kọ ẹkọ Keu, ti wọn si ma n ṣere laarin adugbo ti wọn ba pari ẹkọ wọn tan gẹgẹ bi ti ọjọ ti iṣẹlẹ yii waye.

Mọṣalaaṣi yii ni awọn ọmọ naa ti pari ẹkọ Keu, ki wọn to ba oku wọn ninu ọkọ

Oríṣun àwòrán, Screeshot

Àkọlé àwòrán, Mọṣalaaṣi yii ni awọn ọmọ naa ti pari ẹkọ Keu, ki wọn to ba oku wọn ninu ọkọ

Ati pe wọn kii ṣere de inu ọgba ile naa, nitori ko si ẹni to n gbe nibẹ yatọ si iya arugbo naa ti ko dabi ẹni pe ara rẹ ya daadaa.