Kidnapped Baptist Church Members: Àwọn ọmọ ìjọ Emmanuel Baptist Church tí wọ́n jí gbé ní Kaduna ti gba ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, De Town-Cryer
Awọn eeyan bii márùndínláàdọ́rin to jẹ ọmọ ijọ onitẹbọmi ti awọn janduku ji gbe ni ipinlẹ Kaduna ti gba itusilẹ.
Wọn ji awọn eeyan naa gbe lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 yii lẹyin ti awọn janduku ọhun ya bo ile ijọsin wọn, Emmanuel Baptist Chuch, to wa ni Kakau Daji, ni jọba ibilẹ Chikun.
Ọjọ diẹ ti wọn ti ji awọn eeyan naa gbe ni awọn janduku naa pa meji lara wọn.
- Lórí ọ̀rọ̀ Sylvester Oromoni, a kò ní dáké títí ìdájọ́ òtító yóò fi jọba - Gómínà Ifeanyi Okowa
- Aṣọ ń pe aṣọ rán níṣẹ́ ni lónìí nílé ìjọsìn Wolii Sotitobire lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tú olùdásílẹ̀ wọn sílẹ̀
- Ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Itunu Babalola kó tó di olóògbé tí wọ́n ń fi òkú rẹ̀ ránṣẹ́ sílé...
- Awọn gbajumọ akọrin ati oṣere tiata obinrin Naijiria sọ nipa idẹyẹsi lọwọ awọn ọkunrin
- Nàìjíríà ko ni lè wọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ̀sì nítori ẹ̀ya Covid-19 Omicron
- Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí ọmọ mi, Sylvester Oromoni sọ fún wa nìyí nínú ìrọra kí ó tó kú, òní ni ọjọ́ ìbí rẹ̀!
- Wo ohun tí àwọn ọmọ Naijiria sọ lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College, Sylvester Onoromi
- Ṣé lóòtọ́ ni ajínigbé sọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjí di iṣu ní Ibadan?
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn òbí ọmọ ọdún 15 tó yìnbọn pa èèyàn mẹ́rin nílé ẹ̀kọ́
Lọjọ Abamẹta ni awọn eeyan ọhun, ti ọmọde atawọn obinrin wa lara wọn, gba itusilẹ, ti wọn si ko wọn lọ si ijọ Albarkar Baptist Church nibi ti wọn pade awọn mọlẹbi wọn.
Ọkan lara awọn mọlẹbi awọn eeyan naa sọ fun awọn akọroyin pe awọn san owo itusilẹ ki awọn eeyan naa to gab itusilẹ.
Ẹwẹ, kọmiṣọna eto abo abẹle ipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan ni awọn ọmọ ogun ti fa awọn eeyan ọhun le ijọba lọwọ ipinlẹ naa lọwọ lọna ati mu ko rọrun fun wọn lati pada sile wọn.
O fi kun pe wọn ti kọkọ ko awọn eeyan naa lọ si ile iwosan fun itọju to peye.
Amọ Aruwan sọ pe oun ko le sọ boya awọn ajinigbe gba owo itusilẹ ki wọn jọwọ awọn eeyan ọhun.















