Bashorun High School Ibadan: Ṣé lóòtọ́ ni ajínigbé sọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjí di iṣu ní Ibadan?

Ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Others

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti fesi si iroyin to n ja ranyin nilẹ pe ajinigbe kan ti ọwọ tẹ sọ akẹkọọ meji ni ileẹkọ Bashorun High School, Ibadan di isu.

Kọmiṣọnna eto ẹkọ nipinlẹ Oyo, Rahman Abdul-Raheem ni ko si otitọ kankan ninu iroyin naa lasiko to n ba awọn akẹkọọ, obi ati awọn ojulumọ sọrọ ni ileẹkọ naa.

Raheem lo ṣe abẹwo si ileẹkọ naa lati ṣewadii iṣẹlẹ naa ti ohun ja ranyin lori ẹrọ ayelujara.

Iroyin to n ja ranyin naa ni ajinigbe lo sọ awọn akẹkọọ meji da isu pẹlu ''pampers'' ti wọn ko tii lo.

Iroyin ọhun fikun un pe awọn ẹṣọ alaabo labẹle ni wọn fi panpẹ mu ajinigbe naa ni agbegbe Bode Wasinmi-Bashorun, ti ko jina si ileẹkọ naa.

Eleyii da ipaya silẹ fun awọn eniyan ni agbegbe naa paapaa awọn obi ti wọn fi ọmọ si ileewe ọhun.

Amọ kọmiṣọnna fun eto ẹkọ nipinlẹ naa ni iwadii awọn pẹlu awọn alaṣẹ ileewe naa fihan pe ko si akẹkọọ kankan to di awati ni ileewe naa.

Bakan naa ni kọmiṣọnna pe fun alaafia ati ki awọn eniyan fi ọkan balẹ.

Àkọlé fídíò, Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí

O ni ẹṣọ alaabo naa ti bẹrẹ iwadii pẹrẹwu lori iṣẹlẹ naa lati fi idi iṣẹlẹ to waye gan an lede fun awọn eniyan.

Kọmiṣọnna fun eto ẹkọ naa fi da awọn araalu loju pe eto aabo awọn araalu jẹwọn logun, ti igbiyanju si n lọ lati ri pe aabo to daju wa fun awọn araalu.