Int'l Day for Persons with Disability: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣetán láti máa gbàwọn àkàndá ẹ̀dá ṣíṣẹ́

Awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, NPF

Ọga agba orilẹ ede Naijiria, Usman Alkali Baba ti kede pe ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣetan lati maa gba awọn to ni ipenija ara ṣiṣẹ.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita lati ọwọ alukoro rẹ, CP Frank Mba, loni to jẹ ayajọ awọn to ni ipenija ara, ni ọrọ yii ti suyọ.

IGP Baba ṣalaye pe igbesẹ naa wa ni ibamu pẹlu ṣiṣe iṣẹ ọlọpaa lọna igbalode gẹgẹ bo ṣe ri kari aye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọga ọlọpaa Naijiria ni igbesẹ yii waye lẹyin ọpọ ijiroro pẹlu akọwe agba ajọ to n ri sí ọrọ awọn to ni ipenija ara, Ọgbẹni James David Lalu eyi to ṣabewo sí ọga ọlọpaa ni ọfiisi rẹ niluu Abuja.

Gẹgẹ bi o ti ṣalaye ninu atẹjade ọhun, ọfiisi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni olu ilu ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria to fi mọ Abuja l'awọn eeyn naa yoo ti maa ṣiṣẹ.

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀

O ni eyi yoo fáwọn to n ba n ṣiṣẹ ni ọfiisi yii lanfaani lati ri pe awọn eeyan to ni ipenija ara jẹ anfaani ọlọpaa.

Ọga ọlọpaa tun ṣalaye pe Igbanisiṣẹ awọn akanda ẹda yoo tun dẹkun idẹyẹsi wọn lawujọ.

Bakan naa ni ọga ọlọpaa Naijiria tun buwọ lu akanṣe idanilẹkọ ati igbaradi fawọn eeyan ti ileeṣẹ ọlọpaa ba gba ṣiṣẹ ọhun.

Ileeṣẹ ọlọpaa gbe idanilẹkọ yii silẹ pẹlu ifọwọsowọpọ ajọ NCPWD to n ri sí ọrọ awọn to n gbe pẹlu ipenija ara.

Ọga agba ọlọpaa ti wa pàṣẹ fun gbogbo awọn kọmiṣọnna ọlọpaa l'awọn ipinlẹ at'awọn ọga wọn, AIG lati ṣakoso igbaniwọle awọn to ni ipenija ara ṣiṣẹ ọlọpaa kaakiri Naijiria.

O tun fidi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo maa gbiyanju lati ri pe ẹnikan kàn ko fi ẹtọ awọn to ni ipenija ara dun wọn.

Àkọlé fídíò, Ṣé lọ́òtọ́ ọkọ àti ìyàwọ́ ní Mr & Mrs Kogberegbe? Àṣírí bí a ṣe ń ṣe ètò yìí rèé...

Ẹwẹ, akọwe agba ajọ NCPWD to n ri sí ọrọ awọn to ni ipenija ara, Lalu dupẹ lọwọ ọga ọlọpaa Naijiria.

O ni eto yii mu adinku ba ipenija t'awọn eeyan to ni ipenija ara n koju ni Naijiria.