Covid-19: Ẹ̀dà àrùn Omicron rápálá wọ̀ orílẹ̀èdè 16 ní àgbáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan, orilẹ-ede mẹrinlelogun ni ẹda arun Covid-19 tuntun Omicron ti rapala wọ bayii kaakiri agbaye gẹgẹ bii ọrọ ti ajọ WHO ṣẹṣẹ sọ.
India, Ghana, Saudi Arabia ati UAE wa lara awọn orilẹ-ede to ṣẹṣẹ kede pe awọn ti ri ẹda Omicron naa nilẹ wọn.
Ilẹ Amẹrika, ilẹ Gẹẹsi ati Germany naa ti sọ pe ẹda Covid-19 tuntun naa ti rapala wọ ọdọ awọn.
- Èsì iléẹ̀kọ́ Dowen rèé sí ìkú akẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn òbí rẹ̀ ní àwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn pa nítorí kò darapọ̀ mọ́ wọn!
- N kò fara mọ́ ẹ̀rí Princess, ẹ yọ́ dànú torí kò bá òfin mu - Baba Ijesha yarí nílé ẹjọ́
- Òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ ló sin Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ OAU tó kú sílé ìtura - Agbẹjọ́rò
- “Màá ṣúgbàá gbígba ₦25m ẹ̀tọ́ Baba Suwe lọ́dọ̀ NDLEA lẹ́yìn ikú rẹ̀”
- Abubakar Malami kéde àwọn agbébọn bíi agbésùnmọ̀mí lẹ́yìn ò rẹyìn
Nilẹ Afrika, South Africa lo n leke tente awọn to ti ni ẹda arun naa, bo tilẹ jẹ pe ibẹ ni wọn ti kọkọ ṣawari rẹ ni nnkan bii ọsẹ kan ṣeyin.
Awọn orilẹ-ede tie ẹda Covid-19 Omicron ti rapala wọ ree
Gẹgẹ bii ohun ti ileeṣẹ to n ri si idena itankalẹ ajakalẹ arun nilẹ Afrika, ACDC, sọ, orilẹ-ede marun un ni ẹda arun tuntun naa ti rapala wọ.
Awọn orilẹ-ede naa ree:
South Africa
Aarẹ ajọ eleto ilera ni South Africa, Angelique Coetzee, lo kọkọ sọrọ lori ẹda Omicron nilẹ naa lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin naa ni wọn ṣe ayẹwo ninu laabu, ti wọn si kede pe lootọ ẹda arun naa ti jade, lẹyin eyii ni ajọ WHO kede pe ẹda tuntun naa kii ṣe keremi.
Coetzee ni o bẹrẹ pẹlu alaisan kan ti aarẹ n ṣe pẹlu ara yiyun.
Ẹwẹ, eeyan to le ni ẹgbẹrun mọkanla lo lugbadi ẹda Omicron ọhun laarin wakati mẹrinlelogun.
Botswana
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla ni ileeṣẹ eto ilera Botswana fi ọrọ sita pe awọn naa ti ri ẹda Omicron nile wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn ni awọn eeyan ilẹ okeere to wọ ilẹ ọhun lọjọ Keje, oṣu Kọkanla yii kan naa lo ko arun ọhun wọle.
Ayẹwo fi han pe mẹrin ninu awọn arinrinaji naa ani Covid-19 lasiko ti wọn n mura lati pada si orile¬-ede wọn.
Naijiria
Ọjọ kinni, oṣu Kejila, ọdun 2021 yii ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ ajakalẹ run ni Naijiria, NCDC kede pe ẹda Omicron ti rapala wọ Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọga agba NCDC, Ifedayo Adetifa, sọ pe eeyan meji to wọ Naijiria lati South Africa lo ko ẹda arun naa wọle.
Adetifa ni awọn eeyan meji naa ko si fi apẹrẹ arun naa han rara.
Ghana
Gẹgẹ bii ohun ti ijọba Ghana sọ, awọn eeyan to wọle silẹ naa lati Naijiria ati South Africa lo ko ẹda Omicron wọle.
Ijọba ilẹ ọhun ti wa kan an nipa fun gbogbo oṣiṣẹ ijọba, to fi mọ awọn olukọ atawọn agbofinro lati gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni Kankan.
Ẹwẹ, ajọ WHO sọ pe ko tii si ẹnikẹni to tii padanu ẹmi rẹ nitori ẹda Omicron yii.













