Timothy Adegoke: Àwọn ọ̀dọ́ Eruwa ké sí Buhari, Makinde láti tako kí wọn dabarú ìwádìí ikú olóògbé

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Awọn ọdọ ilu Eruwa nipinlẹ Oyo tii ṣe ilu Timothy Adegoke, akẹkọọ MBA ni fasiti OAU to ku si ile itura Hilton hotel ni Ife, ti ṣe iwọde lati fi ehọnu wọn han lori iṣẹlẹ naa.
Awọn ọdọ ọhún, ti wọn ṣe iwọde ni Ọjọbọ niluu Eruwa sọ pe, idajọ ododo l'awọn n fẹ lori iwadii to n lọ lọwọ lati mọ ohun to ṣe okunfa iku Timothy nile itura Hilton ni Ile Ife.
Wọn ni awọn ti ri pe awọn kan ti fẹ dabaru iwadii ọhun nitori bi ẹjọ naa ṣe n lọ bayii.
- Òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ ló sin Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ OAU tó kú sílé ìtura - Agbẹjọ́rò
- Kí ló ń dá ọlọ́pàá dúró láti gbé Rahmon Adedoyin àti ọmọ rẹ̀ relé ẹjọ́ lórí ikú Timothy Adegoke?
- Kanpe ni òkú Timothy Adegoke wà, wọn kò gé ẹ̀yà ara rẹ̀ - Ọlọ́pàá Osun
- Kọmísánà ọlọ́pàá tú àṣírí bí ọmọ Rahmon Adedoyin ṣe ju òkú Timothy Adegoke sígbó, tó na pápá bora
- Mi ò pààyàn rí láyé, mi ò kí ń ṣe afini ṣòògùn owó, ẹ jọ̀wọ́ dúró dé ìwádìí Ọlọ́pàá - Rahmon Adedoyin tó ni hòtẹ́ẹ̀lì
- Ìyàwó Adedoyin sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe kú sílé ìtura ọkọ rẹ̀ ní Ile Ife
- ''Ó burú jáì pé Ramon Adedoyin tí akẹ́kọ̀ọ́ kú sílé ìtura rẹ̀ tún ń sọ̀rọ̀ lákàtà ọlọ́pàá''
- Àlàyé ọlọ́pàá Osun rèé lórí ọ̀nà tí Rahmon Adedoyin gbà ká ọ̀rọ̀ rẹ̀ sínu fọ́nrán ohùn tó lu ayélujára pa
- Wo Sẹ́nétọ̀ tó fẹ́ gbé bùkátọ̀ iléẹ̀kọ́ ìbejì Timithy Adegoke tó kú sílé ìtura ní Ife
Ọdọ kan to jẹ ọkan lara awọn olufẹhonuhan naa to sọrọ nibi iwọde naa ke pe Aarẹ Muhammadu Buhari ati gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, lati da si ọrọ naa ki idajọ ododo le waye.
Ọdọ naa ti ko darukọ ara rẹ sọ pe inu awọn ko dun bi wọn ṣe pa ọmọ ilu awọn.
"Ìdí niyi ti a fi ko ara wa jọ lati ṣe iwọde nitori a ti ri awọn igbesẹ ti wọn n gbe lati dabaru iwadii to n lọ lọwọ lori ọrọ yii.
Ohun ti a fẹ ni idajọ ododo nitori ẹni to ba fi ida pa eeyan, ida lo yẹ ki wọn fi pa oun naa.
A wa n fi asiko yii ke si Aarẹ Muhammadu Buhari, gomina Seyi Makinde ati ọmọ wa, Adebo Ogundoyin tii ṣe adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo lati ba wa da si ọrọ naa.
A fẹ ki wọn ji giri lati ri pe idajọ ododo waye lori iku ọmọ wa, Timothy.
A si tun fi asiko dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọmọbibi ilu Eruwa ti wọn ti n ṣiṣẹ takuntakun lori ọrọ yii.
A gbadura pe ẹnikẹni ko ni fi iru rẹ gbaa, a ko dẹ ni ri ayọlọ mọ laarin wa.
Ohun ti a n fẹ naa ni idajọ ododo, ko ju bayẹn lọ," ọkan lara awọn oluwọde lo sọ bẹẹ.
Ni bi ọjọ meji sẹyin ni agbẹjọro fun Oloye Rahmon Adedoyin to ni ile itura Hilton hotel ti Adegoke ku si sọ pe, iwadii ti fihan pe awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ife lo sin akẹkọọ MBA fasiti OAU to ku si ile itura naa.
Oloye Adedoyin wa lara awọn afurasi ti ileeṣẹ ọlọpaa ti mu lori iku Timothy Adegoke.




















