Timothy Adegoke: Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Osun ní ọmọbíbí Rahmon Adedoyin tó ni ilé ìtura tí Adegoke kú sí, ló jù òkú rẹ̀ sígbó

Oríṣun àwòrán, Timothy Adegoke/Rahmon Adedoyin/Facebook
Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Osun, Wale Olokode ti ni ọkan lara awọn afurasi ninu iku Timothy Adegoke, to jẹ akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo, ti jẹwọ bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.
Afurasi naa, Roheem Adedoyin lo jẹ ọmọ ẹni to ni ile itura Hiltons Hotels and Resort, Ile-Ife, ni ọlọpaa ni oun lo ṣakoso bi wọn ṣe gbe oku naa kuro ninu ile itura lọ ju si inu igbo.
Ọga ọlọpaa nipinlẹ Osun ni Roheem ni alakoso ile itura naa ti Adegoke ti ku, to si wa nibẹ nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, to si ṣeto bi wọn ṣe gbe oku rẹ kuro ni ile itura naa, ti wọn si lọ sin lai fi to ọlọpaa leti.
- Awuyewuye súyọ lórí fídíò òkú Baba Suwe tó lu ayelujára pa
- N kò rán ẹnikẹ́ni láti pín ìrẹ̀sì àti ẹ̀wà tórí ìbò ààrẹ 2023 - Bola Tinubu figbe ta
- Ọmọbíbí Rahmon Adedoyin tó ni ilé ìtura tí Timothy Adegoke kú sí, ló jù òkú rẹ̀ sígbó - Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Osun
- Àìsí Atúmọ̀ èdè Yorùbá sí Gẹ̀ẹ́sì pagidínà ìgbẹ́jọ́ ọmọlẹ́yìn Sunday Igboho méjì
- Afurasí ológun gbé alága NURTW tẹ́lẹ̀ l‘Oyo pé ó ń ṣe onígbọ̀wọ́ Sunday Igboho
- Buhari, fi Sunday Igboho sílẹ̀, kí ìṣọ̀kan le padà sí Naijiria - Oluwo
Lasiko to n sọrọ lori redio Rave FM, Osogbo ni Olokode ti ni, Roheem ti na papa bora, to si jẹ pe iwadii ọlọpaa lo jẹ ki wọn mọ ibi ti wọn gbe oku naa pamọ si.
''Ọkan lara awọn afurasi jẹwọ pe ọmọ Ramon Adedoyin ti orukọ rẹ n jẹ Roheem Adedoyin to jẹ ọmọ ẹni to ni ile itura naa, ti sa kuro ni ilẹ yii lati igba ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.
''Afurasi naa jẹwọ pe Roheem lo ṣakoso bi wọn ṣe lọ sọ oku arakunrin naa si inu igbo, ti oun naa si tẹle wọn pẹlu oṣiṣẹ agba meji to tẹle wọn lọ si inu igbo.''
''Ko si ẹnikẹni ninu awọn oṣiṣẹ yii to fi ẹjọ sun ọlọpaa, awọn mọlẹbi ti wọn bẹrẹ si ni wa ọkunrin naa, ti awọn ọlọpaa kogberegbe ti wọn si bẹrẹ si ni ṣe iwadii bi arakunrin naa ṣe di awati ninu ile itura, ti wọn si lo ri oku rẹ ninu igbo.''
N ko mọ bi Adedoyin se ka fọnran ohun ara rẹ silẹ lati ahamọ to wa, eyi gba ori ayelujara kan:
Olokode ni oun ko mọ nkankan nipa igbohunsafẹfẹ ti Adedoyin ṣe ni panpẹ ọlọpaa nibi to ti sọ wi pe oun ko jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun.
Amọ nibayii, awọn mọlẹbi ti kesi ileeṣẹ ọlọpaa lati salaye bi Adedoyin ṣe n jaye ọba ni ahamọ ọlọpaa nitori o jẹ ilumọọka ni awujọ.
Agbẹjọro mọlẹbi naa, Adekilekun ni awọn ti kesi ọlọpaa lati ri pe idajọ ododo jọba ni iwadii yii lai ṣe ojusaaju fun ẹnikẹni lori iṣẹlẹ yii.
O ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori bi Adedoyin ṣe bẹrẹ si ni ṣe igbohunsafẹfẹ ninu ahamọ lasiko to wa ni ikawọ wọn.
''Ohun itiju lo jasi pẹlu bi ọpọlọpọ ọrọ ṣe n jade lati ẹnu awọn eniyan ti wọn fẹ gbeja ẹni to ni ile itura ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, Rahmon Adedoyin wi pe ko ṣẹ ẹsẹ kankan.''
''Ohun ti a fẹ ni ki onikaluku duro de idajọ ileẹjọ lori iṣẹlẹ yii lati sọ ẹni to jẹbi ẹsun yii tabi bẹẹkọ lai lo ọna ẹburu lati ma a ke gbajare si awọn eniyan lawujọ lati gbe ija wọn ja.''

Bí àyẹ̀wò òkú Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU tó kú sílé ìtura, ṣe wáyé rèé

Oríṣun àwòrán, Timothy Adegoke/Rahmon Adedoyin/Facebook
Iroyin ni awọn onimọ nipa ayẹwo oku naa de ọgba ile iwosan ẹkọni Osun State University Teaching Hospital (UNIOSUNTH), Osogbo, ni nkan bi aago meji ọsan ni Ọjọ Aje
Awọn onimọ nipa ayẹwo oku ti ṣayẹwo iru iku to pa akẹkọkunrin ni fasiti Ọbafemi Awolowo University, ti Ile Ife.
Iroyin ni awọn onimọ nipa ayẹwo oku naa de ọgba ile iwosan ẹkọsẹ isegun fasiti ipinlẹ Osun (UNIOSUNTH) to wa nilu Osogbo, ni nkan bi aago meji ọsan Ọjọ Aje.
- Kanpe ni òkú Timothy Adegoke wà, wọn kò gé ẹ̀yà ara rẹ̀ - Ọlọ́pàá Osun
- ''Ó burú jáì pé Ramon Adedoyin tí akẹ́kọ̀ọ́ kú sílé ìtura rẹ̀ tún ń sọ̀rọ̀ lákàtà ọlọ́pàá''
- Mi ò pààyàn rí láyé, mi ò kí ń ṣe afini ṣòògùn owó, ẹ jọ̀wọ́ dúró dé ìwádìí Ọlọ́pàá - Rahmon Adedoyin tó ni hòtẹ́ẹ̀lì
- Ilééṣé ọlọ́pàá Osun tí mú Olùdarí ilé ìtura tí Akẹ́kòó fásìtì OAU ti dédé pòórá
- Ìyàwó Adedoyin sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe kú sílé ìtura ọkọ rẹ̀ ní Ile Ife
Amọ awọn onisegun naa ko gba awọn mọlẹbi, ati awọn oniroyin laaye si agbegbe naa, amọ wọn n woye bi o ṣe nlọ lati ileẹjọ.
Ninu ọrọ rẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Yemisi Opalola sọ fun awọn oniroyin pe wọn ko tete ṣe ayẹwo oku naa nitori awọn mọlẹbi sọ wi pe awọn fẹ ki aṣoju awọn wa nibẹ lasiko ayẹwo naa.
Bakan naa ni iroyin ni pe awọn mọlẹbi fa onimọ nipa ayẹwo oku ti yoo soju wọn silẹ, nigba ti awọn alayẹwo oku naa wa nibẹ ni ibi ayẹwo naa, ti gbogbo wọn si ri bi wọn ṣe ṣe ayẹwo naa.
Dokita Waheed Oluogun lati fasiti imọ ẹkọ iṣegun naa lo ṣe ayẹwo oku Timothy.
Amọ dokita naa ni awọn ọlọpaa ni oun yoo fi abajade ayẹwo naa ṣọwọ si ni nikan bi ọsẹ meji si mẹta si isinyii, ti esi ayẹwo naa ba jade.
Ninu ọrọ ẹbi Adegoke, eyi ti agbẹjọro Naheem Adekilekun kede sita, wọn ni o di igba ti ayẹwo oku naa ba jade ki awọn to sọ ọrọ kankan lori rẹ.
Adekilekun wa parọwa si awọn ileeṣẹ ọlọpaa pe ki wọn maṣe ṣe ojusaaju lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si fi iya to tọ jẹ ẹni to ṣe iṣẹ laabi yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Awuyewuye súyọ lórí fídíò òkú Baba Suwe tó lu ayelujára pa
- Afurasí ológun gbé alága NURTW tẹ́lẹ̀ l‘Oyo pé ó ń ṣe onígbọ̀wọ́ Sunday Igboho
- Bí Buhari bá fi Sunday Igboho sílẹ̀, ìṣọ̀kan yóò padà sí Naijiria - Oluwo
- "Àgbà Yorùbá dalẹ̀ Sunday Igboho, wọ́n fi sílẹ̀ bíi ọmọ òrukàn"
- Àìsí Atúmọ̀ èdè Yorùbá sí Gẹ̀ẹ́sì pagidínà ìgbẹ́jọ́ ọmọlẹ́yìn Sunday Igboho méjì
- Naijiria yóò dojúrú tí Buhari bá tú Nnamdi Kanu sílẹ̀ - Ẹgbẹ́ àpapọ̀ l‘Ókè Ọya
- "Buhari, Sanwo-Olu, ẹ kọ̀wé fipò sílẹ̀ torí àwọn ọ̀dọ́ tó kú lásìkò ìwọ́de EndSARS"
- Ìjọba Eko fi ọwọ́ ọlà gbá ìyá Jumoke lójú ní ₦1m àti ilé tó hááyà fún - Agbẹjọ́rò
Timothy Adegoke ni wọn lo tẹ ọkọ leti wa si ipinlẹ Osun lati wa ṣe idanwo ni fasiti Obafemi Awolowo OAU , ki o to di awati ni Ọjọ Keje, Oṣu Kọkanla, ọdun 2021.
Lẹyin naa ni awọn ọlọpaa ri oku rẹ ninu igbo ni agbegbe to wa loju ọna Ede si Ife, lasiko ti wọn bẹrẹ si ni wa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn afurasi mẹfa to jẹ oṣiṣẹ ile itura Hilton Hotels and Resort ati Ramon Adedoyin to ni ile itura naa. ni wọn ti mu lẹyin ti iwadii fihan pe lootọ ni Adegoke wa si ile itura naa lati gba yara, ki o to di awati.


















