Nothern Coalition Group: Àpapọ̀ ẹgbẹ́ ní Ariwa Naijiria sọ pé kí Buhari má gbìyànjú láti tú Kanu sílẹ̀

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Nnamdi kanu

Agbarijọpọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ to wa ni Ariwa Naijiria, The Coalition of Nothern Groups (CNG) ti sọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari pe ko gbọdọ gbe igbesẹ lati tu Nnamdi Kanu, olori ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ Biafra silẹ.

Opin ọsẹ to kọja ni iroyin sọ pe Aarẹ Buhari ni oun yoo ronu nipa itusilẹ Kanu, lasiko ti awọn agbaagba kan lati ilẹ Igbo ṣe abẹwo si nitori ọrọ rẹ.

Lọwọlọwọ, Nnamdi Kanu wa ni ahamọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS nilu Abuja.

Nibi ipade akọroyin kan ti wọn se lọjọ Aje, agbẹnusọ ẹgbẹ CNG, Abdulazeez Suleiman, sọ pe awọn eniyan Ariwa yoo di ẹbi "ẹjẹ awọn alaiṣẹ ti iṣẹ ọwọ Kanu sọ di ero ọrun" ru Buhari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Suleiman ni laarin ọdun 2017 si 2020, Kanu ṣe agbatẹru pipa eeyan to le ni ẹgbẹfa, ti wọn wa lati ẹkun Ariwa ṣugbọn ti wọn n gbe ni ilẹ Igbo, ti wọn si tun ba awọn dukia wọn to jẹ olowo iyebiye jẹ.

Bakan naa lo sọ p,e ko din ni irinwo oṣiṣẹ alaabo ti Kanu ati ẹgbẹ IPOB ti pa.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke: Màmá olóògbé ní ògó ilé àwọn ni wọ́n pa, ikú rẹ̀ kò gbọdọ̀ já sásán

"Ti Buhari ba fi le gbiyanju lati tu Kanu silẹ lai fi iya jẹ ẹ labẹ ofin, eyi yoo sọ Naijiria di orilẹ-ede ti ko si ibọwọ fun ofin rara, nibi ti ọdaran oriṣiriṣiri yoo ti ma a hu iwakiwa, ti wọn o si ran awọn adari ẹya wọn lati ba wọn bẹbẹ."

Bẹẹ ba gbagbe, awọn agbaagba to jẹ ẹya Igbo, eyi ti Mbazulike Amaechi lewaju wọn, lo lọ se abẹwo si ọdọ aarẹ Buhari lọjọ Ẹti to kọja, lati bẹbẹ fun itusilẹ asaaju ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu to wa ni ahamọ DSS lọwọ lọwọ.