Buhari on Nnamdi Kanu: Buhari ní òun á gbé ìtúsílẹ̀ Nnamdi Kanu yẹ̀wò, ṣùgbọ́n yóò le díẹ̀

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency
Aarẹ Buhari ti jẹ ko di mimọ pe o ṣeeṣe ki oun gbe ọrọ itusilẹ aṣiwaju ẹgbẹ ajijagbara ilẹ Igbo, IpoB, Nnamdi Kanu yẹwo.
Itusilẹ nnamdi Kanu, to wa ni ahamọ ijọba bayii lẹyin ti wọn fi ẹsun iditẹ gbajọba atawọn ẹsun nlanla miran kan, wa lara ẹbẹ ti awọn agbaagba ẹya Igbo to bẹ aarẹ wo nileeṣẹ aarẹ nilu Abuja gbe ka iwaju Aarẹ Muhammadu Buhari lasiko abẹwo wọn.
- Wọ́n lù mí bíi ẹní máa kú, wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn nílé Princess kí n tó dé àgọ́ ọlọ́pàá - Baba Ijesha
- Buhari buwọ́lu N656 bílíọ́nù owó ìdólà fún àwọn ìpínlẹ̀
- Ìkúnlẹ̀ abiyamọ ò! Wo bí arábìnrin yìí ṣé bínú dá omi gbígbóná s'ará ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀
- Lẹ́yìn Titi Masha, Kwam 1 gbé ìyàwó tuntun, Emmanuella Ropo l'Abeokuta, bó ṣe lọ rèé
Amọṣa aarẹ ni ibeere wọn naa wuwo pupọ fun oun gẹgẹ bi aṣiwaju orilẹede Naijiria nitori atunbọtan rẹ le gidigidi nitori pe ohun ko tii figbakan ri da si ọrs awọn ẹka iṣedajọ lorilẹede Naijiria.
"Ohun ti ẹ bere fun yii lagbara gan ni, ṣugbọn maa gbe e yẹwo."
Aarẹ Buhari ni nigba ti Nnamdi Kanu kọkọ sa mọ ofin lọwọ, a rii mu pada wale ni oun fi woo pe a dara ko koju ilana gbogbo to yẹ niwaju ile ẹjọ. Ki oun pẹlu lọ ro ẹjọ awijare rẹ niwaju ile ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency
Ninu ọrọ tirẹ, alagba Mbazulike Amaechi ti ṣiwaju igbimọ awọn agbaagba ẹya Igbo naa ṣalaye pe yoo dara gidigidi lati lo ọna oṣelu dipo ọna ologun lati yanju ọrọ Ijọba apapọ ati Nnamdi Kanu.
O ni bi ijọba apapọ ba lee tu nnamdi Kanu silẹ 'ko ni sọ awọn nnkan to n sọ tẹlẹ mọ."
Alagba Amaechi ni gẹgẹ bi agbalagba ti ọjọ ti lọ lori rẹ, ko wu oun lati fi ile aye silẹ laijẹ pe alaafia jọba lorilẹede abinibi oun.
Lara awsn miran to wa ni igbimọ naa ni gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Anambra, Chukwuemeka Ezeife, Biṣọbu Sunday Onuoha ti ijọ eleto Methodist, Amofin Goddy Uwazurike, aarẹ ẹgbẹ ajafẹtọ Igbo nigbakanri, Aka Ikenga ati Tagbo Mbazulike Amaechi.












