Ààrẹ Buhari buwọ́lu N656 bílíọ́nù gbèsè owó ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ìpínlẹ̀

Oríṣun àwòrán, NIGERIA PRESIDENCY
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu owo to le ni ẹgbẹ̀ta miliọnu Naira (656.112) gẹgẹ bi owo iranwọ fun àwọn ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria.
Níbi ipade ìbímọ to n sa mojuto ọrọ aje Naijiria ni Igbakeji Aare, Yemi Osinbajo, ti kede igbesẹ naa.
- Pásítọ̀ onísọjí tó fí ipá bá olóyún oṣù mẹ́jọ sùn ní Ondo, ohun tí a mọ̀ rèé
- Lẹ́yìn Titi Masha, Kwam 1 gbé ìyàwó tuntun, Emmanuella Ropo l'Abeokuta, bó ṣe lọ rèé
- Wọ́n yọ Nàìjíríà kúrò lára àwọn orílẹ̀èdè alákatakítí ẹ̀sì lágbàáyé, ọ̀pẹ́ Buhari sí Anthony Bliken rèé
- Gbas-gbos ti ń wáyé ṣáájú ìdìbò sí ipò gómìnà Osun, kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàrín Aregbesola, Oyetola?
Agbẹnusọ fun Osinbajo, Laolu Akanbi, sọ ninu atẹjade kan pe owo to le ni biliọnu mejidinlogun Naira (18.225) ni ipinlẹ kọọkan yoo gba, ti wọn o si san gbese naa laarin ọgbọn ọdun pẹlu èlé ìdá mẹsan.
Ileesẹ aare sọ pe oun gbe igbesẹ naa lati ran awọn ìjọba ipinlẹ lọwọ ki wọn o le ri owo gbọ bukaata, paapaa fun gbese owo eto isuna ti wọn jẹ tẹlẹ.
Minisita eto inawo ati isuna, Ọmọwe Zainab Ahmed, sọ fun igbimọ naa pe banki apapọ Naijiria, CBN, ni yoo samojuto owo yiya naa.
Ẹẹmẹfa si ni awọn ipinlẹ yoo gba owo naa laarin oṣù mẹfa.








