Kwam 1's new wife: Emmanuella Ropo di aya Kwam 1, bó ṣe lọ rèé

Kwam 1 ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, PM News Nigeria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lẹyin ọdun mẹta ti gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde ti ọpọ mọ si Kwam 1 fẹ iyawo rẹ kekere, Titi Masha ni Ijebu-Ode, agogo igbeyawo tun ti dun laarin olorin naa ati ọmọ ẹlẹ kan, Emmanuella Ropo.

Lọjọru ọsẹ ni igbeyawo Kwam 1 waye niluu Abeokuta pẹlu apọnbeporẹ arẹwa obinrin, Aderopo Emmanuella ti gbogbo ilu mi titi.

Ropo jẹ ẹni to ti le ni Ogoji ọdun lọjọ ori nigba ti Wasiu Ayinde jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgọta to si ti ni ọmọ to le ni ogoji latọdọ ọpọlọpọ obinrin.

Amọṣa kii ṣe pe o fẹ gbogbo wọn sile.

Iyawo ti wọn mọ mọ Kwam 1 ju ni Yewande to n gbe ni Canada ti wọn si ni ọmọ marun papọ.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Itunu Babalọla Death: Ìjọba Nàíjìríà fèsì sí ìbéèrè Baba Itunu Babalola lórí òkú ọmọ rẹ̀!
Emmanuella Ropo àti Kwam 1

Oríṣun àwòrán, Kwam1

Wasiu ko fi bo rara gẹgẹ bo ṣe maa n pe ara rẹ ni alaya pupọ eyi ti oloyinbo n pe ni Polygamist to si ni oun ko tii de ipo ti Fela Anikulapo gbajugbaja olorin to ti d'oloogbe to ni akọsilẹ iyawo mẹtadinlọgbọn.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Oṣu to kọja ni iroyin brẹ si ni ta si awọn eeyan leti pe Kwam 1 tun ti fẹ ṣe iyawo pẹlu ẹlẹ tuntun yii. Koda o fi orin kan sori ayelujara ninu eyi to ti n pe e ni "Ajike Okin ati Neulla Ajike Mi".

Emmanuella naa fi ọrọ ifẹ rẹ sita nipa igbeyawo naa to n gbadura fun ẹmi gigun ninu ifẹ ati idunu fun oun ati Kwam 1.

Emmanuella Ropo àti Kwam 1

Oríṣun àwòrán, EmMANUELLA Ropo/Instagram

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si:

Àkọlé fídíò, Itunu Babalọla Death:Àgbáyé ẹ gbà mí, mọ fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ mí! ìyà yí tí pọ̀jù