Itunu Babalọla Death: 'Baba Itunu Babalola bèrè òkú ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ wa, a ó gbé e wálé lẹ́yìn àyẹ̀wò irú ikú tó pa á'
Ijọba orilẹede Naijiria ti ṣeleri pe gbogbo ohun ti Baba Itunu Babalola ba fẹ lori iku ọmọ rẹ ni awọn yoo ṣe fun.
Eyi ko sẹyin bi Baba Itunu Babalola ṣe ke gbajare sita lori fidio ifọrọwanilẹwo pẹ̀lu BBC Yoruba pe oun fẹ idajọ ododo lori iku to pa ọmọ oun ni ẹwọn.
Ati wi pe, oun fẹ ki wọn ba oun gbe oku ọmọ ohun wale, ki wọn ma se oku rẹ basubasu si orilẹede Ivory Coast to ku si.
Ninu esi wọn, adari ajọ to n risi ọrọ awọn ọmọ Naijiria ni okeere, Abike Dabiri-Erewa ni awọn n gbe igbeṣẹ lori rẹ amọ ijọba fẹ ṣe ayẹwo oku naa finifini lati mọ iru iku to pa arabinrin naa.
Lẹyin ti wọn kọkọ gbe e jade pe aisan suga lo ṣekupa arabinrin naa, amọ baba rẹ ni saka ni ara ọmọ oun da.
Abike fikun pe lara iṣoro ti awọn koju lori ọrọ arabinrin Itunu Babalola ni pe lẹyin ọdun meji to ti wa ni ẹwọn ni awọn ṣẹṣẹ gbọ nipa iṣẹlẹ naa.
- Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, Ijọba Eko sọrọ lórí àbọ̀ ìgbìmọ̀ igbẹjọ́ lórí #EndSARS
- Ilééṣé ọlọ́pàá Osun tí mú Olùdarí ilé ìtura tí Akẹ́kòó fásìtì OAU ti dédé pòórá
- 'Ó ṣeéṣe kí ẹ̀dà ìwé àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ EndSARS tó lu sórí ayúlujára yàtọ̀ sí èyí t'íjọba yóò gbé jáde'
- Òhun tí Cute Abiola ṣe rèé táa fí sọ ọ́ sí àhámọ́ - Iléeṣẹ́ Navy
- Ìdí nìyí tí mo fi kọ́ ilé ẹ́kọ́ fáwọn Daran-daran Fulani - Sheikh Gumi
Ati wi pe kii ṣe orukọ abisọ ti wọn mọ Itunu si lorilẹede Naijiria ni oun jẹ ni Ivory Coast, nitori Becky Paul lo wa lori ẹjọ to wa ni ileẹjọ ni Ivory Coast.
Laipẹ yii ni awọn mọlẹbi arabinrin Itunu Babalọla gbọ nipa iku rẹ ni ọgba ẹwọn to ti n koju ẹsun ifi ọmọ ṣe owo ẹru, amọ awọn obi rẹ ni irọ ni wọn pa mọ.


