EndSARS panel report: Rinu Oduala, adarí ìwọ́de EndSARS dúró lórí pé bí irọ́ àwọn ìjọba bá lọ lógún ọdún, òtítọ́ á lékè

Oríṣun àwòrán, other/savvyrinu/instagram
Iwe akọsilẹ abajade iwadii igbimọ lori aṣemaṣe awọn ọlọpaa ati iṣẹlẹ to waye ni Lekki Toll gate logunjọ oṣu kẹwaa ọdun 2020, to wa nigboro lori ayelujara, eleyi to n fa ọpọlọpọ awuyewuye bayii yats si eleyi to wa lọwọ ijọba ipinlẹ Eko.
Ọkan lara awọn ajafẹtọ to runpa runsẹ si iwọde naa lọdun 2020, Rinu Oduala lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba.
O ni lootọ ni ẹda kan jade sita lara abajade iwadii awọn igbimọ naa ṣugbọn ohun to wa ninu rẹ lee yatọ si ohun to wa ninu eyi ti wọn gbe kalẹ fun gomina ipinlẹ Eko.
- Òhun tí Cute Abiola ṣe rèé táa fí sọ ọ́ sí àhámọ́ - Iléeṣẹ́ Navy
- Irọ́ ńlá lẹ pa, mi ò kó ọ̀rọ̀ mi jẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Toll Gate - Lai Mohammed
- 'Gómìnà Sanwo-Olu kò tíì ka ìwé àbájáde ìwádìí EndSARS'
- 'Kò lòdì sí ofin láti yàn mọ̀lẹ́bí sí ipò, àmọ́ ṣé ọ̀mọ̀ Akeredolu kójú'òsùwọ̀n ìpò tí bàbá rẹ̀ yàn án sí?' - Onímọ̀ òṣèlú
- Ọnà ayédèrú ní wọn gbà gbé àbájáde ìwádìí Endsars tàwọn èèyàn n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jáde - Ọgágun Irabor
- Àwọn ọlọ́jà ní Oyingbo ṣe iwọ́de, wọ́n ní Folashade Tinubu ti ọjà pa torí N5m
O ṣalaye pe idi ni pe awọn oniruuru afikun ati ayọkuro lo lee ti waye laarin ẹda to lu sita ati eyi ti wọn fountẹ lu gbe le gomina lọwọ.
Arabinrin Rinu Oduala tun tẹsiwaju lati sọ pe ko ni ya awọn ajafẹtọ to lewaju iwọde EndSARS lọdun 2020 lẹnu bi abajade iwe ilana ijọba iyẹn 'White paper' lori abọ iwadii igbimọ naa ba yatọ si ohun to wa ninu ẹda iwe iwadii to lu sita.
"Ijọba ko ni so okun mọ ara rẹ lẹsẹ, Ekeji ni pe a ti gbọ nipa oriṣiriṣi igbimọ sẹyin bii igbimọ oputa atigbimọ oriṣiriṣi. Gbogbo awọn aba tawọn igbimọ yii n gbe jade, ṣe ijọba maa tẹle awọn aba naa? Pupọ ninu awọn ti orukọ wọn jade ninu ẹda to lu sita yii la ri pe inu ijọba ni wọn wa, ṣe ijọba yoo lee fi wọn jofin?'
O ni nitori pe ọpọ ọmọ Naijiria mọ irufẹ ijọba ti wọn ni pe lati ipilẹ ni wọn ti fẹ doju ọrọ ohun to ṣẹlẹ ru nipa pipariwo kiri agbaye pe ko si ikọlu kankan nibẹ ati pe ko si eeyan kankan to ku.
Rinu Oduala ni ohun to han si gbogbo eeyan kaakiri ni nitoripe gbogbo agbaye lo ri ohun to ṣẹlẹ ati bi awọn agbofinro ṣe huwa ipa si awọn araalu paapaa awọn ọdọ lorilẹede Naijiria lasiko naa.
Lori ọrọ aṣuwọn ifowopamọsi rẹ ti ijọba gbẹsẹ le

Oríṣun àwòrán, lasg
Lori ọrọ aṣuwọn ifowopamọsi rẹ ti ijọba gbẹsẹ le nigba naa, arabinrin Rinu Oduala ṣalaye pe lẹyin oniruru ifigagbaga ofin laarin amofin agba Fẹmi Falana ati ijsba Naijiria, wọn ti gbe ẹsẹ kuro lori aṣunwọn ifowopamọsi naa.
O ni gbogbo ẹsun igbesunmọmi ati awọn ẹsun miran ti ijọba fi kan oun atawọn miran lasiko iwọde naa ni wọn ko lee fi idi rẹ mulẹ to si mu ki amofinagba Fẹmi Falana o fariga pe niwọn igba ti wọn ko ba ti le ṣe eyi ki wọn gbẹsẹ ati apa kuro lori awọn aṣuwọn naa lo tọ.
O ni wọn ti gbẹsẹ kuro lori ti toun, ṣugbọn wọn ṣi gbẹsẹ le awọn miran.
Lori ọrọ awọn to n ja fun ipinya orilẹede Naiijiria ati idasilẹ orilẹede ẹya kọọkan
Lori ọrọ awọn to n ja fun ipinya orilẹede Naiijiria ati idasilẹ orilẹ€de ẹya wọn, arabinrin Rinu ṣalaye pe bi idajọ ododo ko ba fidi mulẹ, ti awọn kan n ṣegbe ti wọn si n tẹ oju ofin mọlẹ, ko si bi awọn kan to ni ẹhonu ko ṣe ni pariwo sita pe ara n kan wọn ti wọn yoo si fẹ beere fun idaduro tiwọn.
O ni oun ti oun farams ni igbesẹ ti yoo fun awọn ọdọ ni ọjọ ọla to dara.














