Endsars panel report: Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, Ijọba Eko Sọrọ lórí ìjábọ̀ ìgbìmọ̀ igbẹjọ́ lórí #EndSARS

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Eko nipasẹ Kọmísọ́nà fun ọrọ to ń lọ ati Ilana eto, Ọgbẹni Gbenga Omotoso, ti fesi si iroyin igbimọ EndSARS to n lọ kaakiri.
Igbimọ Idajọ ti ipinlẹ Eko lori atunṣe fun awọn ti o farapa nípa iwa ipa àti ifiya jẹni ti SARS ati awon nnkan tó jọ mọ ti fi ijabọ abajade rẹ ranṣẹ si Gomina Babajide Sanwo-Olu ni ọjọ Aje.
Komisona ninu àtẹ̀jáde kan ni Ọjọbọ, ṣe akiyesi pe awọn ariyanjiyan to ń lọ nigboro lori ijabọ naa ko wúlò.
Ẹwẹ, Gbenga Omotoso ni ó ṣe pàtàkì fún àwọn eniyan lati yago fun bíbu ẹnu atẹ lu isẹ ribiribi àti ero rere ti ijọba ni sì iṣeto igbimọ yii, àti àwọn ìpinnu wọn lati ṣe iṣẹ rẹ lẹkunrẹrẹ - Igbimọ náà se amujáde òtítọ́ nínú ìwádìí wọn.
“Ni ibamu pẹlu òfin tribunal ọdún 2015, a ti ṣeto igbimọ kan lati gbe Iwe kan tí yoo salaye ìgbésẹ̀ jade lórí nnkan ti ijọbọ ń pinnu. Ni akoko ti o yẹ, ijọba yoo jẹ ki a mọ àwọn ero rẹ lori gbogbo awọn ọrọ ti igbimọ naa gbé kalẹ ninu iwe ti won yoo kọ, " gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ.
Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju - 'Gómìnà Sanwo-Olu kò tíì ka ìwé àbájáde ìwádìí EndSARS'
Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ sọ pe 'Gómìnà Sanwo-Olu kò tíì ka ìwé àbájáde ìwádìí EndSARS' torinaa ko ni le fesi si ohun tawọn eniyan n gbe ka.
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ko tii ka iwe abajade iwadi igbimọ iwadii EndSARS, iwa kotọ awọn ọlọpaa ati wahala to waye ni Lekki Toll gate.
Eyi loun ti ọgbẹni Gboyega Akoṣile, agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Eko sọ.
O sọrọ yii pẹlu awuyewuye lori ẹda iwe abajade iwadii naa kan to lu sita.
Gẹgẹ bi Akọṣile ṣe sọ, gbogbo abọ iwadii igbimọ naa ni ijọba yoo fi sita laifi igbakan bọkan ninu.
- Òhun tí Cute Abiola ṣe rèé táa fí sọ ọ́ sí àhámọ́ - Iléeṣẹ́ Navy
- Àwọn ọlọ́jà ní Oyingbo ṣe iwọ́de, wọ́n ní Folashade Tinubu ti ọjà pa torí N5m
- 'Kò sí nkan tó burú nínú bí Akeredolu ṣe yan ọmọ rẹ̀ sí ipò! Ayé ń ṣe irú ẹ̀'
- Ọnà ayédèrú ní wọn gbà gbé àbájáde ìwádìí Endsars tàwọn èèyàn n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jáde - Ọgágun Irabor
"Gomina ko tii ri iwe iwadii naa, ko tilẹ tii yẹ ẹ wo. O ṣa ti gbe igbimọ ẹlẹni mẹrin kalẹ lati yẹẹ wo ki wọn si gbe iwe amuṣẹya kan jade.'
Ki lo wa ni inu ẹda iwe abajade iwadii naa to wa
Ẹda iwe iwadii naa ti igbimọ oluwadi ti ijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ yọju rẹ sita pe ileeṣẹ ọmọogun Naijiria mọọmọ kọju ibọn si awọn oluwọde to wa ni Lekki Toll gate ni ogunjọ oṣu kẹwaa ọdun 2020 ṣugbọn ti wọn gbiyanju lati da ọwọ boo mọlẹ.
Iwe abajade naa darukọ eeyan mejidinlaadọta gẹgẹ bi awọn to faragba nibi iṣẹlẹ lekki Toll gate ninu eyi ti mọkanla ti ku, mẹrin si di eyi ti a n wa, gẹgẹ bi ẹda abajade naa ṣe sọ.
Bakan naa lo tun yọ oju rẹ sita pe lẹyin ti awọn ologun pari yinyinbọn nibẹ lawọn ọlọpaa naa bọ sibẹ lati palẹ gbogbo nnkan mọ lati palẹ awọn ọta ibọn ti wọn yin nibẹ mọ.
Awọn to ṣoju wọn n ṣalaye pe ọkọ akẹru nla ni wọn fi ko oku awọn eeyan ti wọn yinbọn pa nibẹ.
Ileeṣẹ ọmọogun ni awọn ko yin ibọn ni Lekki Toll gate lasiko iwọde naa rara.
Amọṣa, gomina Sanwo-Olu ti ṣeleri lati dari iwe naa iwadii naa si igbimọ ọrọ aje apapọ orilẹede.
Amerika sọ̀rọ̀ sókè lórí àbájáde ìwádìí #EndSARS, Ó ní ìjọba gbọ́dọ̀ tètè wá nǹkan ṣe

Oríṣun àwòrán, U.S. Mission Nigeria/BBC
Ijọba ilẹ Amẹrika ti ke si ijọba ipinlẹ Eko ati ijọba apapọ orilẹede Naijiria pe ko tete ṣe ohun to ba yẹ lori abajade iwadii igbimọ oluwadi ti wọn gbe kalẹ lati wadii awọn ẹsun iwa kotọ ti wọn fi kan ẹka ileeṣẹ ọlọpaa SARS ati ohun to ṣẹlẹ ni Lekki Toll gate lọdun 2020.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ aṣoju ijọba orilẹede Amẹrika ni Naijiria fi sita, "Orilẹede Amẹrika dunnu si ipari iṣẹ igbimọ oluwadii ati gbigbe abajade wọn kalẹ."
O ni oun ti awọn n reti bayii ni ki ijọba ipinlẹ Eko gbe igbesẹ lori rẹ gẹgẹ bi ara ọna ati ṣe ohun to tọ nipa iwọde #EndSARS naa ati awọn iṣẹlẹ to waye ni Lekki Tollgate ni ogunjọ oṣu kẹwaa ọdun 2020.
Orilẹede Amẹrika ni awsn iṣẹlẹ naa yọ oju oniruuru ifisun jade eleyi to kọju si awọn eeyan kan lẹka ileeṣẹ alaabo.
O wa fi kun pe ijọba ipinlẹ Eko ati ijọba apapọ gbọdọ gbe igbesẹ to yẹ lori iwa familete ki ntutọ gbogbo tawọn oṣiṣẹ alaabo hu lati tan ẹdun ọkan awọn ti wọn rẹ jẹ tabi idile wọn.
Kò ní sí ọ̀rọ̀ òkú òru lórí àbájáde ìwádìí nípa #EndSARS, Lekki Toll Gate, Sanwo-Olu ṣèlérí fárá Eko

Oríṣun àwòrán, lasg
Ni ọjọ Aje, ọjọ karundinlogun oṣu kọkanla ọdun 2021 ni igbimọ oluwadi ti ijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ lori ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan awọn ọlọpaa SARS ati ohun to ṣẹlẹ ni Tollgate logunjọ oṣu kẹwaa ọdun 2020.
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti fi ọkan awọn eeyan balẹ pe ko si ọrọ oku oru kankan bo ti wulẹomọ lori ọrọ abajade iwadii igbimọ naa ati wi pe oun ti gbe igbimọ ẹlẹni mẹran kan kalẹ lati gbe iwe ilana ijọba, - White paper, jade lori rẹ lọna ati lee mu ki ijọba ipinlẹ Eko gbe igbesẹ gbogbo to ba yẹ lori rẹ ni kiakia.
- 'Ọ́lọ́run mo dúpẹ́ o pé wọn ò kà mí mọ́ ẹni tó ti wọlẹ̀ báyìí níbi afẹ́fẹ́ gáàsì tó búgbàmù'
- Àwọn ajínigbé pa èèyàn méjì l’Akure, ẹnìkan móríbọ́, ẹnìkan ṣì wà ní ìkáwọ́ wọn
- Gbèdékè ọ̀ṣẹ̀ mẹ́ta la fún ìjọba Buhari láti sanwó oṣù òṣìṣẹ́, ìyanṣẹ́lódì ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ASUU ń rúgbó bọ̀!
- Ilé ẹ̀kọ́ Fásítì Unilorin fọwọ́ òsì júwe ilé fún akẹ́kòó tó lù olùkọ lálùbami
- Lóòtọ́ ni wọ́n de òkú táa gbé jáde nínú odò Asa, Ilorin lọ́wọ́ àti ẹnu - Ilééṣé ọlọ́pàá
Ni alẹ ọjọ Aje ni kete lẹyin ti igbimọ naa gbe abajade iwadi rẹ iwaju gomina ipinlẹ Eko ni iji awuyewuye lori abajade naa ti jade sigboro pe ẹda abajade naa kan ti lu sita eyi to sọ pe lootọ lawsn ologun yin ibọn ni Tollgate ti ọpọ si ku ti awọn miran si fara ṣeṣe.
Amọṣa gomina Sanwo-Olu ni gbogbo abajade iwadii naa ni wọn yoo fi sita fun gbogbo araalu lati ri lai fi igba kan bọkan ninu.
O fi kun un pe ni kete ti awọn igbimọ tẹẹkoto ẹlẹni mẹrin naa ba ti gbe iwe ilana ijọba, - White paper, jade lori rẹ laarin ọsẹ meji ni igbimọ iṣejọba ipinlẹ Eko ti wọn yoo si tun fi ṣọwọ si igbimọ ọrọ aje apapọ orilẹede Naijiria.
O fi da awọn eeyan ipinlẹ Eko ati olugbe ipinlẹ naa loju pe ilana ofin ati ifẹ araalu ni wọn yoo tẹle lori ọna naa dipo ohun ti awọn kan n sọ pe wọn lee ṣe loku oru.
Gomina Sanwo-Olu ni ko si igba kan ti oun tabi ijọba oun gbiyanju ati doju iṣẹ igbimọ iwadii naa ru.
Ninu ọrọ tirẹ to sọ, alaga igbimọ naa, Adajọfẹyinti Okuwobi ni owo to to irinwo o le mẹwaa miliọnu Naira ni wọn buwọlu fun sisan fun aadọrin eeyan gẹgẹ bi owo gba maa binu lori awọn iwa familete n tutọ awọn ọlọpaa.
O fi kun pe iwe ẹhonu ojilelugba o din marun (235) ni igbimọ naa tẹwọ gba, ninu eyi to jẹ pe mẹrinla pere lo da lori iṣẹlẹ to waye ni agbagbe Lekki Tollgate ni ipinlẹ Eko.

















