Unilorin Student Beats Lecturer: Iléẹ̀kọ́ fásitì Ilorin tí jáwé máa lọ sílé rẹ fún akẹ́kòó tó dá sẹ̀ríà fún lẹ́kíṣọ́rà rẹ̀

Captain Walz, Aworan Unilorin

Oríṣun àwòrán, Unilorin fm

Yunifasiti ilu Ilorin ti le akẹkọọ to lu olukọ rẹ lalubami, Salaudeen Aanuoluwa Waliu kuro nile ẹkọ wọn.

Eyi waye lẹyin to jẹjọ niwaju igbimọ ibawi fasiti naa lọjọ Aje tii ṣe ọjọ Kẹẹdogun oṣu yi.

Ọgbẹni Kunle Akogun to jẹ agbodegba ile ẹkọ naa lo fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC.

O ni lẹyin atotonu ati ayẹwo ẹri to wa niwaju wọn igbimọ naa ri pe Waliu jẹbi ẹsun pe o ṣiwọ lu olukọ rẹ.

Amọ ṣa Akogun ni anfaani wa fun lati pe ẹjọ kotẹmilọrun laarin ọjọ mejidinlaadọta ti wọn gbe idajọ yi kalẹ.

O tẹsiwaju pe awọn ti fa ọrọ naa le ọlọpaa lọwọ lati tẹsiwaju iwadii ati ijẹjọ lori ẹsun ti wọn ba ri pe o tọ labẹ ofin.

Bi a ko ba gbagbe, iroyin gbode pe arakunrin akẹkọọ lẹka imọ sayẹnsi tawọn eeyan mọ si Captain Walz ṣadede lọ ba olukọ rẹ lọfisi to si lu lalubami.

Olukọ naa arabinrin Zakariyyah la gbọ pe o ti n gba itọju ti ara rẹ si ti n ya nile iwosan ti wọn gbe lọ