Itunu Babalola: Ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n láì ṣẹ̀ ní Cote D'Ivoire ti kú, ìjọba Nàìjíríà fàáké kọ́rí

Oríṣun àwòrán, David Hundeyin/facebook
Agba adura l'awọn Yoruba maa n gba pe "a ko ni ri alakoba."
Ọmọ Naijiria kan, Itunu Babalola, to jẹ oniṣowo niluu Bondoukou lorilẹede Cote D'Ivoire ti wọn ju si ẹwọn lai ṣẹ ti jade laye bayii.
Akọroyin kan, David Hundeyin lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ loju opo Facebook rẹ.
Gẹgẹ bi o ti ṣalaye, Itunu ku lẹyin to ko arun kan ni ọgba ẹwọn to wà.
"Iroyin to n tẹ mi lọwọ lati orilẹede Cote D'Ivoire ti sọ pe Itunu Babalola ti ku sẹwon.
Gbogbo ileri ajọ NIDCOM to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, Abike Dabiri-Erewa to jẹ ọga ajọ naa, ati ileri ijọba ipinlẹ Oyo, ti jasi pabo.
Gbogbo eeyan lo jẹbi ọrọ iku Itunu, ọmọ Naijiria mi tun ti tẹri gbaṣọ," Hundeyin lo gbara ta bẹẹ.
Ohun tí a gbọ tẹlẹ ni pe Itunu dero ẹwọn ni Cote D'Ivoire nitori o kọ lati gba ẹgbẹrun lọnà ọgọrun owo riba tawọn ọlọpaa ni ko gba fun iṣẹlẹ ọmọkunrin kan to ja a lole nigba to wa si Naijiria.
Iroyin sọ pe awọn ọlọpaa dunkoko mọ Itunu pe awon yoo da ṣeria fun un ti ko ba gba owo ti awọn fun un lati bo ẹjọ ọmọkunrin to ji ẹru rẹ ko mọlẹ.
Iroyin naa sọ pe ẹbi ọga ọlọpaa to wa lori ẹjọ naa ni ọmọkunrin to jale nile Itunu i ṣe.
Idi gan an niyii ti ọga ọlọpaa ọhun ṣe fun ni owo ko le gbagbe ọrọ naa, ṣugbọn o ni oun o gba owo.
Gẹgẹ bi iroyin naa ṣe sọ lọdun 2019, awọn ọlọpaa wa ẹsun si Itunu lẹsẹ pe o n ṣe fayawọ eeyan wa sí orilẹ-ede Cote D'Ivoire.
Bi Itunu ṣe dero atimọle niyii ti o si pada di ero ẹwọn lai mọwọ, lai mẹsẹ.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo kepe ijọba Naijiria lati yọ Itunu ninu ọfin to wa ni Cote D'Ivoire.
Ijọba Naijiria nipasẹ ajọ NIDCOM ti sọ pe iwadii fihan pe Itunu ko mọ ohun kan nipa ẹsun ti wọn fi kan an.
Wọn ní akoba ni wọn fi ọrọ naa ṣe fun Itunu.
Ẹwẹ, ijọba apapọ ti pàṣẹ pé kí wọn ṣe ayẹwo oku Itunu lati mọ ohun to ṣeku pa a gan an.
Ajọ NIDCOM lo kede ọrọ yii ni ọjọ kẹẹdogun oṣu kọkanla ọdun 2022 yii.
Dabiri-Erewa ni iku Itunu ṣeni laanu nitori pe ijọba ti sanwo fun agbẹjọro to yoo ṣakoso ẹjo kotẹmilọrun lori ọrọ rẹ ni Cote D'Ivoire.
Ẹwọn ogun ọdun ni wọn ran Itunu lori ohun ti ko mo ohun kan nipa rẹ.














