Yollywood: Gbajúmọ̀ òṣèré, Ijebu ní Ọgbọ́n lòun fi ń yẹra fún gbọ́yísọ̀yí lágbo àwọn òṣèré

Ijebuu

Oríṣun àwòrán, Ijebuu/instagram

Gbajumọ apanilẹrin lagbo sinima ede Yoruba, Tayọ Amokade ti ọpọ eeyan mọ si Ijebu ti ṣalaye fun araye pe ati dide goke ko rọgbọ fun oun nitoripe awọn iṣẹ ti ọpọ ko fi oju rena ni oun ti ṣe ki itanṣan ọla to tan si oun.

Ijẹbu ṣalaye ninu ifọrọwanilẹwo kan pe iṣẹ ẹrọ amunawa, jẹnẹretọ titunṣe loun n ṣe ki oun to di ilumọọka oṣere.

Bakan naa lo ṣalaye nipa oniruuru ijakulẹ ti oun dojukọ ki aye to mọ oun.

"Iṣẹ ẹrọ amunawa, jẹnẹretọ titunṣe ni mo kọkọ fi bẹrẹ. Mo jẹ eeyan ti kii fi iṣẹ jafara rara, gbogbo anfani ti mo ba si ri ni mo maa n mu lọkunkundun."

Ijebuu

Oríṣun àwòrán, Ijebuu/instagram

Bakan naa lo tun sọrọ lori awọn awuyewuye to maa n waye lagbo awọn oṣere to si ni, oun n gbiyanju ni igba gbogbo lati yẹra fun ẹrẹ awuyewuye to n waye lẹka naa.

O ni bi o ti wulẹ wu ki oṣere sare to lati yẹera fun awọn gbọyisọyi lagbo amuludun, awọn iṣẹlẹ ori ayelujara ti jẹ ko ṣoro pupọ.