Sani Dangote : Àbúrò oníṣòwò Aliko Dangote tó jẹ́ igbákejì Dangote Group jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Dangote Group
Awọn to gbọ iroyin naa kọkọ ro pe Aliko Dangote ilumọọka oniṣowo lo jade laye.
Amọ kii ṣe Aliko, Sani Dangote aburo rẹ to tun jẹ igbakeji aarẹ ileeṣẹ Dangote lo ki duniya pe o di gbere.
Lọjọ Aiku yi ni Sani jade laye ti ileeṣẹ Dangote ko si sọ pato ohun to ṣokunfa iku rẹ.
Iroyin to n tẹwa lọwọ sọ pe orileede Amẹrika lo ku si lẹyin aisan ọlọjọ pipẹ.
Ileeṣẹ Dangote ṣapejuwe iku rẹ yi gẹgẹ bi eleyi to fọwọ kan ni lẹmi.
Ikú Ọ̀gágun Dzarma Zirkusu kan mi l'égungun gidi torí Nàìjíríà ló ń jà fún tí ISWAP fi pa á - Buhari

Oríṣun àwòrán, DANGOTE GROUP
Ta ni Sani Dangote ko to jade laye
Sani Dangote ko lokiki to ẹgbọn rẹ Aliko Dangote ṣugbọn oniṣowo to munadoko loun naa ṣe.
Ṣaaju iku rẹ, o ni ipin ninu awọn ẹka karakata to fi mọ ẹka ọgbin,ile ifowopamọ ati ipese ọja.
O jẹ ọga lawọn ileeṣẹ to fi mọ Nigerian Textile Mills Plc, Nutra Sweet Limited, Gum Arabic Limited ati Dangote Textile Mills Limited.
Bẹẹ naa la gbọ pe o jẹ ọkan lara igbimọ alaṣẹ Alsan Insurance Brokers, Dan-Hydro Company Limited, Dansa Food Processing Company Limited ati Dangote Farms Limited.
Koda o tun di ipo igbakeji alaga ẹgbẹ African Gum Arabic Producers Association to si tun jẹ aarẹ ẹgbẹ Lagos Polo Club lẹẹmeji ọtọọtọ.
Sani jẹ elere idaraya Polo ko dantọ
Nitori bo ṣe jẹ oludari to munadoko, wọn fi ipo da lọla gẹgẹ bi oludari agba ileeṣẹ orileede Romania ni Naijiria.
Orisirisi ipo ati oye lo si dimu to fi mọ ti Chartered Institute of Shipping of Nigeria ti wọn tun fi jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn to n pese ajilẹ ni Naijiria,FERSAN.














