Brigadier General Dzarma Zirkusu: Ààrẹ Buhari fọn rere nípa Ọ̀gágun Dzarma Zirkusu àtàwọn ológun mẹ́ta tí ISWAP pa

Ọgagun Dzarma Zirkusu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Aarẹ Muhammadu Buhari n ṣọfọ Ọgagun atawọn ọmọ ogun mẹta mii to ku ninu ikọlu pẹlu awọn ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Islam, ISWAP lasiko ti wọn n doju ija kọ ara wọn niluu Borno.

Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria fi ikede iku wọn sita lọjọ Abamẹta pe Ọgagun Dzarma Zirkusu to jẹ adari ikọ ogun, ọ̀wọ́ kejidinlọgbọn atawọn sọja mẹta mii ti wọn jọ kagbako iku lasiko ti wọn n jagun pẹlu awọn ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Islamic State West Africa Province (ISWAP) ni ilu Askira, ijọba ibilẹ Uba nipinlẹ Borno.

Lẹyin wakati mẹrinlelogun ti ileeṣẹ ogun ṣe ikede yii ni aarẹ Buhari fi atẹjade sita ninu eyi to ti n kan sara si jijẹ Akin Ọgagun Dzarma atawọn ti wọn jọ ku, o ni pe "wọn ti ṣe ifiraẹni jin to lagbara ju ninu gbigbogun ti sunmọmi lorilẹede Naijiria.

Atẹjade naa to ti ọwọ oluranlọwọ pataki fun aarẹ Garba Shehu wa, aarẹ Buhari iṣẹlẹ iku wọn ja oun laya koda to tun da ibanujẹ saarin awọn ologun Naijiria paapaa bi orilẹede yii ṣe n koju idunkoko mọni ni iha Ila Oorun-Ariwa orilẹede.

Ninu atẹjade ileeṣẹ ologun, wọn ni ikọ ọmọ ogun da abo bo agbegbe naa daadaa amọ ṣiṣe ikọlu si ibudo awọn ologun ti n kọ eeyan lominu bayii ni Naijiria ggẹ eleyii to ṣẹlẹ yii naa ṣe jẹ ni ibudo wọn.

Atẹjade naa ni Ọga agba awọn ologun oriilẹ ti fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si ẹbi ati ara awọn oloogbe naa.

Ọgagun Faruk Yahaya tun ti paṣẹ pe ki ikọ ọm ogun tunbọ ko ina mọ ṣiṣe ikọlu titi wọn yoo fi le awọn agbesunmọmi ọhun to n sa mu.

Àkọlé fídíò, Wo òkè ìṣẹ̀mbáyé Abanijorin yìí l'Ekiti tó máa ń bá ọ̀kọ̀ rìn lójú pópó tó tún ní ilé ìwòran orí ìtàgé nínú rẹ̀