ISWAP attack army base in Borno: Iléeṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà ti dárúkọ ọ̀gágun táwọn agbébọn ISWAP pa ní Borno lọ́jọ́ Sátidé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọgagun ileeṣẹ ọmọogun Naijiria kan atawọn ṣọja mẹta miran ni awsn agbebọn ti pa lasiko ikọlu kan to waye ni ipinlẹ Borno.
Awọn agbebọn tawọn eeyan furasi pe wọn jẹ ọmọ agbebọn Islamic West Africa Province (ISWAP ) kọlu awọn ọmọogun Naijiria ni ibudo ologun kan nibẹ.
Atẹjade kan eyi ti alukoro ileeṣẹ ọmọ ogun oriilẹ, Onyema Nwachukwu fi sita ni irọlẹ sjọ Satide ṣalaye pe orukọ ọgagun agba naa ni Dzarma Zirkusu ati pe oun atawọn ọmọogun mẹta miran padanu ẹmi wọn ni ijọba ibilẹ Askira/Uba nibi ti ibudo ologun naa wa.
- Ọmọ Fásitì Unilorin lu lẹ́kíṣọ́rà obìnrin lálùbami torí ó ríi lójú orun
- Wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàrín Annie, ìyàwó 2face àti Pero, ìyá ọmọ rẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ oṣù méjì sẹ́yìn
- Wo ọ̀nà tuntun tí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà gbé kalẹ̀ tí o fi lè di onílé
- 'Mi ò fìgbà kankan fura pé ọkọ mi lè fi ọmọ wa ṣe òògùn owó'
- Ẹgbẹ́ Afenifere kò gbàgbọ́ nínú yíyapa kúrò ní Naijiria - Ayo Adebanjo
Ileeṣẹ ologun ṣalaye ninu atẹjade naa eyi to tẹ BBC News Yoruba lọwọ pe awọn ọmọogun Naijiria ti ṣẹ awọn agbebọn ISWAP naa lẹyin ṣugbọn ija ṣi n gbona girigiri nibẹ.
Lasiko ti wọn fi gbe atẹjade naa sita, baluu ogun A-Jet marun lawọn ẹka ọmọogun ofurufu fi ranṣẹ.

Oríṣun àwòrán, HQ Nigerian Army/facebook/screnshot
Bakan naa ni wọn tun ran ọkọ ogun A-29, ọkọ Dragon combat meji ti wọn fi ba ọkọ agbebọn mẹsan ati ọkọ ayẹta APC kan to jẹ tawọn agbebọn naa jẹ.
Bakan naa ni olori ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ ni Naijiria, Ọgagun agba Faruk Yahaya ti wa ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi awọn ọmọogun to sun loju ija naa.
O si ke sawọn ọmọogun naa lati ma tẹti loju ija naa titi ti wọn yoo fi rẹyin awọn agbebọn ISWAP naa.













