Annie, ìyàwó 2face tọrọ àforíjì, ṣùgbọ́n Pero, ìyá ọmọ 2face ní àfi kó san N500 fún ọ̀rọ̀ tó sọ nípa òun

Annie idibia, 2face idibia ati Pero Adeniyi

Oríṣun àwòrán, Annieidibia/official2baba/perosaiyemi/instagram

Gbajumọ oṣere sinima ni to tun jẹ iyawo gbajumọ olorin takasufe, 2Face, Annie idibia ti rawọ ẹbẹ sawọn si ọkọ rẹ atawọn miran to ta ẹrẹ si lori ayelujara loṣu kẹsan ọdun yii.

Annie gbe atẹjade aforijin yii jade loju opo instagram rẹ lọjọ Satide, ọjọ kẹtala oṣu kọkanla ọdun 2021 lasiko to n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ. O ni alaafia nikan loun n fẹ gẹgẹ bi ẹbun ọjọ ibi oun.

Loṣu kẹsan ọdun yii ni Annie pariwo le ọkọ rẹ, 2face atawọn ẹbi rẹ lori loori ayelujara ti ọrọ ọhun si si eyi ti wọn n gba bi ẹni n gba igba ọti nigba naa.

Annie fi ẹsun kan 2face pe o lọ n sun si abẹ orule kan naa pẹlu Pero, to bi ọmọ fun gbajumọ akọrin takasufe naa. Bakan naa lo tun pariwo faye pe awọn ẹbi 2face ko fẹran oun lainaani gbogbo ilakaka oun lati ṣe ohun ti wọn fẹ.

Ohun ti Annie idibia kọ soju opo instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, Annieidibia/instagram

Nibayii Annie ti pa ẹnu ọrọ da o, o si ti tuba lọwọ ọkọ rẹ atawọn ẹbi ọkọ rẹ pe ki wọn foriji oun nitori iṣẹlẹ naa.

"Ilana tuntun niyi fun mi, yoo si wu mi lati bẹrẹ lakọtun. Oniruuru nnkan lo ti ṣẹlẹ lọdun yii, ọpọ ire ati ọpọ ẹdun ọkan."

Pero ti pẹjọ lori ọrọ ti Annie sọ si

Àkọlé fídíò, Wo òkè ìṣẹ̀mbáyé Abanijorin yìí l'Ekiti tó máa ń bá ọ̀kọ̀ rìn lójú pópó tó tún ní ilé ìwòran orí ìtàgé nínú rẹ̀

Amọṣa ni bayii, Pero Adeniyi to jẹ iya awọn ọmọ 2face kan ti wa fi iwe ipẹjọ ranṣẹ si Annie bayi pe afi ko san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira fun ibanilorukọ jẹ.

Ninu ẹjọ to pe naa lawọn agbẹjọro rẹ ti tọka si awọn ọrọ to sọ loju opo Instagram nibi to ti n darukọ pe ọkọ rẹ 2face pe o n "digba di agbọn rẹ lọ sorilẹede Amẹrika lati lọ ri obinrin naa atawọn ọmọ rẹ"

Wọn ni ọrọ rẹ naa n ro onibara awọn, iyẹnPero Adeniyi ni aṣọ "obinrin oniwakiwa"