Amotekun Ondo: Ìwádìí ń tèsíwájú lórí afurasí ajínigbé tó n múra bíi wère ní gáréèjì Akure

Oríṣun àwòrán, Facebook/Amotekun
Ọwọ palaba arakunrin kan to n dibọn bii were lati maa fi ji awọn eeyan gbe ti ṣegi nipinlẹ Ondo.
Gẹgẹ bi iroyin taa ri ka lati ileeṣẹ iroyin Naijiria Legit.ng,n ilu Akure ni ikọ Amọtẹkun ti mu Labram Ibrahim.
A gbọ pe Gareeji ọkọ to wa ni Akure ni ẹni ọgbọn ọdun yi ti n rinrin gberegbere kaakiri ki ọwọ to tẹẹ.
- 'Ọ̀rọ̀ Amotekun ti dàrú bíi ẹsẹ̀ télọ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo'
- Àgbékalẹ̀ Amotekun dára torí agbára òògùn àwọn baba wa kò dínkù tàbí parẹ́ - Peter Fatomilola
- 'Bí ẹni gbọ́ ikú bàbá rẹ̀ ló rí lásìkò tí a gbọ́ pé Akeredolu gbé owó ilé ẹ̀kọ́ wa sí ₦2.245m'
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ olórí pátápátá fún àwọn ajínigbé kan l'Ekiti
Ninu ọrọ awọn to n taja ni gareeji naa, wọn sọ fun ileeṣẹ iroyin PM News pe ''ṣaaju ki wọn to mu Ibrahim, niṣe lo maa n rin kaakiri gareeji Akure si orita Itanla''
Wọn tẹsiwaju pe lọpọ igba ni ọkọ ayọkẹlẹ jiipu kan ma n wa lati gbe Ibrahim lọ.
''Ihuwasi rẹ yii lo mu ki awọn eeyan fura sii ti wọn si korajọ lati lu''
Nigba ti ileeṣẹ BBC Yoruba kan si ọga agba ajọ Amọtẹkun ni Ondo Adeleye Olusanyero, ko sọ pato ibi ti arakunrin naa wa bayi.
Yatọ si pe ko sọrọ boya arakunrin naa wa ni ọdọ awọn tabi ko si,Adeleye ni awọn ṣi n tẹsiwaju pẹlu iwadii ati pe bawọn ba pari awọn yoo fi to akọroyin leti.
''Ni kete taa ba ti ni iroyin miran si nipa iṣẹlẹ yi ati iwadii wa, a o fi to yin leti''lọrọ to sọ kẹyin ki o to pari ifọrọwanilẹnuwo naa















