Oke Abanijorin in Ekiti: Òjò kò rọ̀ sórí òkè yìí rí àmọ́ inú gbọ̀ngàn rẹ̀ tutù minimini

Àkọlé fídíò, Wo òkè ìṣẹ̀mbáyé Abanijorin yìí l'Ekiti tó máa ń bá ọ̀kọ̀ rìn lójú pópó tó tún ní ilé ìwòran orí ìtàgé nínú rẹ̀

Ori Oke naa wa ni ilu Iyin-Ekiti ni ipinlẹ̀ Ekiti. Abanijorin ni wọn n pe e fun idi to da yatọ gidi gidi.

Ọba ilu Iyin-Ekiti, Ọba Adeniyi Ajakaye sọ fun BBC Yoruba pe bi eeyan ba n rin loju popo ninu ilu naa, a dabi ẹni pe oke naa n ba eeyan rin lọ ni.

"Koda titi di isinsiyii, ti ẹ ba wa ninu ọkọ ti ẹ n wa a lọ, a dabi ẹni pe ẹ jọ n lọ ni ti oke naa si n tẹle yin lọ nitori titobi rẹ.

Oke Abanijorin

Laye igba ti ọna ṣi jẹ tooro ti wọn o tii ṣe opopona nla ọlọda, bi eeyan ba n rin lọ, yoo dabi pe ẹ́yin ati oke yii jọ n lọ ni, idi niyii ti a fi n pee ni Oke Abanijorin".

Lori oke yii kan naa ni awọn nkan amọọmọ da ti awọn ara ilu naa pe ni nkan agba iyanu ti Eledumare da.

Fun apẹrẹ lori oke naa ni ẹni to n ṣafihan ohun gbogbo fun BBC Yoruba pe ojo kii rọ sibẹ ko si bi ojo naa ṣe rọ̀ to.

Gbọngan nla kan to ri bii gbọngan olobiri aye ti aye ode oni ti wọn n pe ni Amphi Theatre wa labẹ okuta nla kan lori oke yii to si ni ijoko okuta to lee gba eeyan irinwo eyi ti wọn ba nibẹ to ti wa ni tito kalẹ.

Koda wọn ni lati inu ilẹ ni omi tutu ti n mu ibẹ tutu bii pe wọn gbe ẹrọ amule-tutu sibẹ.

Yato fun eyi, wọn ba awọn nkankan to n fi apẹrẹ han bii pe awọn eeyan kan ti gbe lori oke yii ri bii, oju ọlọta, awọn koko ati abọ iṣẹmbaye.

Oluyin ti ilu Ekiti sọ fun BBC Yoruba pe iyanu nla ni Ọlọrun fi ta awọn lọrẹ ni ilu naa ti ọpọlọpọ eeyan kaakiri agbaye si le wa maa lo fun igbafẹ. Oke yii ga to iwọn bata ẹẹdẹgbẹrun to si gba akọroyin wa to irin wakati kan lati de oke rẹ pẹlu awọn ti wọn jọ lọ.