Metre price increase: Kí nìdí tí àjọ tó ń mójútó pínpín iná ọba ṣe fikún owó Metre?

Oṣiṣẹ Amunawa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n mojuto pinpin ina ọba lorilẹede Naijiria, (NERC) ni awọn ti fọwọ si atunṣe tuntun ti wọn ṣe pe ki owo metre to n muna wa goke sii.

Ajọ NERC ni awọn buwọlu igbesẹ yii ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin awọn apinna ati apapọ awọn to n moju tan pinpin ina ọba.

Ajọ naa ni ipinu awọn yii da lori ipo ti ọrọ aje orilẹede wa lọwọ lọwọ. Wọn si tun ṣe afikun owo yii gẹgẹ bi orilẹede ṣe n tiraka lati mu ayipada ba ẹka imuna wa.

Àkọlé fídíò, Wo òkè ìṣẹ̀mbáyé Abanijorin yìí l'Ekiti tó máa ń bá ọ̀kọ̀ rìn lójú pópó tó tún ní ilé ìwòran orí ìtàgé nínú rẹ̀

Lati le ri iye owo yii muṣẹ, ajọ NERC ni awọn kan woye ayipada to ba pasiparọ owo ilẹ okere ati lilọ soke ọrọ aje lati inu ayẹwo ti wọ́n ṣe kẹyin lọdun 2020.

Lara ayipada ti wọn ṣe lọtẹ yii ni lati ṣi gbogbo awọn onibara lati kuro lorii metre ti wọn yoo maa mu iwe ina wa si ki wọn maa san owo iye ina ti wọn ba fẹ lo eyi ti wọn n pe ni Prepaid bayii.

Ipa wo ni yoo ko lori owo ina ni Naijiria?

Bi gbogbo nkan ṣe n lọ na bayii, iru biili iwe ina tawọn ọmọ Naijiria n gba jẹ nkan ti ọpọ wọn naa ko lee ṣalaye tori ko ye wọn bi awọn oṣiṣẹ amunawa ṣe n ṣee.

Iwe ina ti wọn maa n mu wa fun awọn to n lo metre analọọgi tabi ti ko ni metre ti n fa wahala kaakiri Naijiria lọpọ igba.

Eyi si maa n jẹ ki ọpọlọpọ to n lo ina ma fẹ san owo ina ti wọn jẹ.

Wọn ni lilo Apoti ina Pepaid ni ọna abayọ ti ileeṣẹ to n pin ina ọba (DisCos) gbé kalẹ bayii si wahala owo ina sisan tori boo ba lo ina iye too ra to ba tan, ko sẹni ti waa da lẹbi.

Amọ ipinu tuntun ti ajọ NERC wa ṣe ni lati fi kun owo metre tori ko le jẹ ọna ati le awọn eeyan lere lati lọ gba Apoti Prepaid.

Àkọlé fídíò, Oluwo dá èsì ńlá padà fún àwọn olórìṣà tó ní kò tọ́ síi kó ní Ọba Yorùbá kìí ṣe ìgbákejì Òrìṣà

Pẹlu iṣoro ọrọ aje to n koju orilẹede bayii ati owo gọbọi to n gori gbogbo nkan ni ọja, o ṣeeṣe ki owo ti wọn fi kun owo metre yoo tun dakun ṣiṣi awọn eeyan lọ sori prepaid ni.

Bakan naao le tun da kun wahala laarin ileeṣẹ DisCos atawọn onibara wọn.

Pẹlu owo to gori rẹ bayii, iye owo ojuna metre kan yoo jẹ N58,661.69 dipo N44,896.17 nigba ti wọn yoo bẹrẹ si ni ta ojuna mẹta ni N109,684.36. Iye owo tuntun yii si tun yatọ si owo ori ọja (VAT) ti wọn yoo fi kun un lasiko ti ẹ ba ra a.