Ọmọ ìyá méjì: A nílò ìránwọ́ ìjọba tàbí aládáni

Àkọlé fídíò, Kwesi àti James f'ẹ̀gẹ́ dárà

Ọmọ ìyá méjì kan ní ẹkùn ìlà-orùn ní orílẹ̀-èdè Ghana tí gbé ìmọ̀ tuntun jáde, bí wọn ṣe mú iná mọ̀namọ́ná jáde lára ẹ̀gẹ́.

James Ansah àti Kwesi Ansah ló gbá ìmọ̀ tuntun ọ̀hún jáde ti wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní 'JK2 table power' èyí ti wọ́n mú jáde láti ara àwọn ǹkan àlòkù bíi ike, gálọ̀nù, igi àti àwọn waya.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ̀gẹ́ tí àwọn míran máa ń pè ní gbàgúdá, jẹ ohun tó wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ adúláwọ, tí wọn sì máa ń lòó fún onírúurú oúnjẹ, bíi fùfú, àmàlà àti ẹ̀bà

Awọn tẹgbọtàbúrò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀ máa ń gbin ẹ̀gẹ́ ju ohujn ti wọ́n nílò, nítori náà àwọn èyí tó bá yẹ kí ó sòfò ní ó wúlò fún àwọn ǹkan tií àwọ́n ń ṣe

Wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀ máa ń gbin ẹ̀gẹ́ ju ohun ti wọ́n nílò lọ, nítori náà, àwọn èyí tó bá yẹ kí ó sòfò ní ó wúlò fún àwọn ǹkan tií àwọ́n ń ṣe.

Wọ́n fí kún pe, pẹ̀lú ìmọ̀ tuntun yìí, àwọn ènìyàn yóò ní àǹfàní láti máa lo ẹ̀gẹ́ láti fún fóònù wọn ní aqgbara, tan iná gílòóbù, àti láti fún radio wọn lágbára ina ọba.

James àti Kwesi sọ pé, àwọn nílò ìránlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ìjọba tàbí àwọn aládáni láti sọ gbogbo àwọn àlòkù ẹ̀gẹ́ ní Ghana di iná àgbára fún ìwúlò lílo iná to dínwo láwọn ilé ìwé.