Ọlọ́pàá Ethiopia: $185,000 ni àwọn ọlọ́ṣa fi sílẹ̀ sá lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn ọlọ́ṣà méjì tí wọ́n lọ jálè ní ilé ìfowópoamọ́ kan ní Ethiopia, há sínú súnkẹ̀rẹ̀-fàkẹrẹ ọkọ̀ ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní olú ìlú orílẹ̀èdè náà, Addis Ababa.
Àwọn olè náà se ìkọlù sí ilé ìfowópamọ́ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abyssinia, ṣùgbọ́n ọwọ́ òfo ni wọ́n mú lọ o, nítórí pé wọ́n sá lọ kí àwọn ọlọ́pàá má bàá mú wọn.
Síbẹ̀síbẹ̀, ọwọ́ tẹ àwọn afunrasí méjì míràn.

Oríṣun àwòrán, AFP
Arákunrin kan tó wà nibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní, bí àwọn ọlọ́ṣà náà ṣe ń sá lọ ní ọkọ́ wọn kọ lu ọkọ̀ tó wà ní iwájú, tí ó sì ta kú. ni wọ́n ba f'ẹsẹ̀ fẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ó ní àwọn ará ìlú fẹ́ mú àwọn ọlọ́ṣà náà, ṣùgbọ̀n ẹ̀rù ń bà wọ́n nítorí pè ọkan lára wọn mú ọ̀bẹ dání.
Agbẹnusọ fun àjọ ọlọ́pàá ìlú nàá ní, bíẹgbẹ̀rún márùndínlàádọ́wàá dọ́là ni àwọn ọlọ́ṣa nàá fi sílẹ̀ sá lọ.








