Ọgá ọlọ́pà: Ìjìyà wọn leè jẹ́ ìfàsẹ́yìn tàbí ìdádúró lẹ́nu isẹ́

awọn ọlọ́pàá méjì tí wọ́n ka owó

Oríṣun àwòrán, Instablog9ja

Àkọlé àwòrán, Wọn ní ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ lé mú ìdápadà tàbí ìdádúró bá àwọn ọlọ́pàá náà lẹ́nu ìṣẹ́.

Kọmíṣọ́na ọlọ́pàá ti ipínlẹ̀ Ẹkó, Edgal Imohimi, ti fi páńpẹ́ mú ọlọ́pàá mẹ́jì kan, tí fídíò kan lórí ìtàkùn àgbàyé safihàn wọn níbi tí wọ́n ti ń ka owó tí wọ́n pa ni ìdi tẹ́tẹ́, tí a mọ̀ sí Baba Ijẹbu,

Ẹ̀ba ilé ìfowópamọ́ Zenith, tó wà ní àdúgbò Opebi, ní Eko ni ìsẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

Fídíò ọ̀hún se àfihàn bí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá méjì náà ṣe n fa sìgá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Imohimi ní wọn yóò ti àwọn méjééjì mọ́lé, tí wọn yóó sì tún dá ẹjọ́ fún wọn.

Nígbà tí fídíò tó ṣàfihan àwọn ọlọ́pàá náà jáde sáyé, àwọn kan ní owó rìbá ni wọ́n n kà, sùgbọ́n àtẹ̀jáde kan láti ọwọ́ agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti Eko, Chike Oti ní, ìwádìí ti fi hàn pé owó Baba Ijebu ni wọ́n ka o.

Oti ní, "Ìyà tí yóò jẹ àwọn ọlọ́pàá náà lé mú ífàsẹ́yìn tàbí ìdádúro pátápátá bá wọn lẹ́nu ìṣẹ́. Ìwa tó burú ni wọ́n hù ní òde gbangba."