Sinikiwe Kademaunga Wedding photos: Ọmọ orílẹ̀-èdè Zimbabwe tí kò ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀ ṣe ìgbéyàwó

Sinikiwe ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/SINIKIWE KADEMAUNGA

Gbajugbaja olugbani ni imọran kan lorilẹ-ede Zimbabwe, Sinikiwe Kademaunga, ti wọn bi lai ni ọwọ ati ẹsẹ, ti ṣe igbeyawo.

Yatọ si pe Sinikiwe ko ni ọwọ ati ẹsẹ, o tun jẹ aràrá.

O fi awsn aworan lati ibi ayẹyẹ igbeyawo rẹ sita lori ayelujara.

Eyi waye lẹyin oṣu diẹ to fi aworan ọkọ afẹsọna rẹ sita fun aye ri lori Instagram, ni ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ.

Olugbani ni imọran ọhun ni ọpọ gbagbọ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 lo ṣe igbeyawo, nitori o kọ deeti naa si abẹ awọn aworan to fi sita.

Awọn aworan naa re e ti Sinikiwe ati ọkọ rẹ ya.

Sinikiwe ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/SINIKIWE KADEMAUNGA

Sinikiwe ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/SINIKIWE KADEMAUNGA

Sinikiwe ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/SINIKIWE KADEMAUNGA

Sinikiwe ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/SINIKIWE KADEMAUNGA

Sinikiwe ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/SINIKIWE KADEMAUNGA

Sinikiwe pẹlu ọkọ rẹ, ati awọn to ba ṣe ẹyẹ igbeyawo

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/SINIKIWE KADEMAUNGA

Ṣaaju ni Sinikiwe ti kede ninu oṣu Keji, ọdun 2021 pe oun ati ololufẹ oun n reti akọbi ọmọ oun, nitori pe oun wa ninu oyun.

Pẹlu aworan to fihan pe o wa ninu oyun lo fi kede iroyin naa.

O kede ninu oṣu Keji pe oun ti loyun akọbi ọmọ oun

Oríṣun àwòrán, Sinikiwe Kademaunga

Àkọlé àwòrán, O kede ninu oṣu Keji pe oun ti loyun akọbi ọmọ oun

Taa ni Sinikiwe Kademaunga?

Orilẹ-ede Zimbabwe ni Sinikiwe ti wa. O jẹ oṣiṣẹ ajọ ẹlẹyinju aanu, o ma n kọ nkan sori ayelujara, o si tun jẹ olugbani ni imọran nipa igbe aye ẹda.

Wọn bi Sinikiwe pẹlu aarun kan, eyi to ṣe idiws fun-un lati dagba boṣe yẹ.

Ọwọ ati ẹsẹ rẹ ko dagba tan, bẹẹni ko ni ọmọ ika ọwọ tabi ti ẹsẹ kankan.

O tun wa a jẹ aràrá.

Ṣugbọn, ko jẹ ki abuku ara rẹ naa ṣe idiwọ fun igbe aye rẹ.

Sinikiwe

O sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu ileeṣẹ iroyin BTV pe o ṣoro fun ẹbi rẹ lati gba kadara lori iru ọmọ to jẹ nigba ti wọn bi.

O ni niṣe ni awọn ọmọde ma n fi oun ṣe yẹyẹ, lasiko to wa ni ọmọde, to ba n gbiyanju lati ba wọn ṣere.

Mi o ki n ri i pe jijẹ alaabọ ara ni nkan ṣe pẹlu òṣì

Sinikiwe Kademaunga sọ fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ni ọdun 2019 pe oun kii ri ara oun gẹgẹ bi ẹni to ni ipenija ara. Ayaafi ni awọn akoko kan tabi iṣẹlẹ to ba ran oun leti.

"Mo jẹ obinrin to gbagbọ pe mo ni afojusun, ti kii si ri aleebu ara gẹgẹ bi ọna lati jẹ oloṣi."

"Ọlọrun fun mi ni ọpọlọ, o fun mi ni ohun gbogbo ti mo nilo lati ṣe awọn nkan mere-mere ti mo fẹ ẹ ṣe."

Sinikiwe le ba eeyan ṣe 'make-up' oju, ati si oju ara rẹ botilẹ jẹ pe ko ni ọwọ.

Sinikiwe Kademaunga re e to n ṣe 'make-up' si oju ara rẹ
Àkọlé àwòrán, Sinikiwe Kademaunga re e to n ṣe 'make-up' si oju ara rẹ

O ni gbigbarale awọn ẹlomiran ma n din iyi ati ẹyẹ kù ni.

O si ma n gba awọn ọdọ to jẹ alaabọ ara bi tiẹ ni imọran pe ko si ohun ti wọn ko le ṣe tabi jẹ ni aye.