Oluwo of Iwo God festival: Mí ò bínú sí àwọn olórìṣà àmọ́...

Àkọlé fídíò, Oluwo dá èsì ńlá padà fún àwọn olórìṣà tó ní kò tọ́ síi kó ní Ọba Yorùbá kìí ṣe ìgbákejì Òrìṣà

"Mò ń ṣe Ọdun Ọga mi ni, Ọga kan ṣoṣo ti mo ni ni Ọlọrun Ọba, ko si si igbakeji fun Ọlọrun."

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti fesi si ọrọ awọn ẹlẹ sin ibilẹ ati awọn ologboni to n tahun sii pe ayẹyẹ ọdun Ọlọrun Ọba to ṣe to wa n fi tabuku awọn Ọba yoruba ku diẹ kaato.

Oluwo fesi nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lẹkunrẹrẹ lati fesi si ohun ti awọn ẹlẹsin ibilẹ n sọ.

O sọ pataki ayẹyẹ Ọdun Ọlọrun Ọba to gbe kalẹ ati bo ṣe tako igbagbọ awọn oloriṣa nipa Ọba ilẹ Yoruba.

"Ọba Yorùbá nìkan ni wọ́n máa ń kí bí wọ́n ṣe ń kí Ọlọ́run, Ọlọrun ni Ka-bi-ọ-ko-si".

O ni Ọlọrun Ọba gangan lo maa n yan Ọba ati pe latọrun leeyan ti maa n gbe ori Ọba waye kii ṣe pe igba to daye tan ni wọn yan an gangan.

"Too bá lórí Ọba, oo lee de ibẹ, Ọlọ́run ò lè gbà kí wọ́n yàn ọ́, àtọ̀run lèèyàn tí ń gbé orí Ọba wá sáyé.

"Ọdún Ọ̀gá mi, Ọlọ́run tó ni mí lèmi ń ṣe".

Oluwo ti Iwo ni oun ko ni nkankan pẹlu awọn oloriṣa amọ koko ọrọ toun ni pe ki wọn ma ṣe gbe ọba si abẹ wọn.

"Ọlọrun Ọba kìí ṣe Òrìṣà Òkè, “Ẹni Orí ṣáà dá” gan ni ìtúmọ Òrìṣà, eyi to tumọ si pe eeyan lo da oriṣa".

Ninu ifọrọwanilẹnuwo yii, Wolii nla kan ni ilu Akure to ba Oluwo pe nibi Ọdun ọhun ni ninu itan oun ko tii ri ilu kan tabi Ọba kankan to ya ọjọ kan sọtọ lati yin Ọlọrun, "eleyi jẹ akọkọ". O si n rọ awọn Ọba to ku naa ki wọn kọ oriṣa silẹ ki wọn sin Ọlọrun Ọba.