Sunday Igboho: A ṣì lè jèbùrẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho àti Kanu tí wọ́n bá kàn sí wa - Malami

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1
Ijọba apapọ Naijiria ti sọ pe awọn ṣi le lo eto oṣelu lati yanju ọrọ oloye Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu.
Agbẹjọro agba ni Naijiria, Abubakar Malami lo fi ọrọ naa lede.
Malami sọ pe ijọba apapọ ko le la oju rẹ oju rẹ silẹ ki awọn kan wa maa da ilu ru mọ ọ lori.
- Kwam 1 dá àwọn tó ń wọ́ ọ tuurutu nílẹ̀ pé ó jẹ́ gbèsè dollar iṣẹ́ orin kan l'Amẹ́rika
- Ẹ yéé gbé ìròyìn òfegè kiri nípa olóògbé Femi Osibona, ó ṣèlérí N25M fún ìjọ mi àmọ́... - Genesis
- Wọ́n ta ìkókó ọmọ mi ní N1M, wọ́n gbé abirùn ọmọ lé mi lọ́wọ́ - Obìrìn aláàrùn ọpọlọ figbe ta
- Wọ́n tún ti yọ òkú èèyàn méjì síi níbi ilé tó wó l'Eko, ó di èèyàn 45 tó kú níbẹ̀ báyìí
- Tí ó kó bá sùn ní aago yìí sí aago yii, àkóbá tí ò ń ṣe fún ìlera ọkàn rẹ nìyìí
- Taa ni arẹ̀wà obìnrin, Emmanuella Ropo tí ìròyìn n sọ pé òun ni ìyàwò K1 tuntun?
- Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrín ọmọ ìyá méjì ni Yobe, ni wọ́n bá gé ara wọn ní apá jábọ́.
- "Ọmọ kan ṣoṣo tó bí fún mi ni wọ́n gún lọ́dún mẹ̀ta sẹ̀yìn kí wọ́n tó gún òun náà pa báyìí"
- Oluwo ti yó tán, ó ń wá bẹ́kùn bẹ́kùn kiri, àwọn òrìṣà tó ń tàbùkù ṣì ń wò ó lọ́wọ́- Ọba Ogboni ìwásẹ̀
- 'Ẹni kọ̀ọ̀kan tó fẹ́ rà nínú ilé alájà 21 tó wó l'Eko ti ṣàdéhùn láti san N206m sí N1.24bn kó tó wó'
- Àrùn jẹjẹrẹ ló mú ìyàwó mi lọ, àmọ́ gbogbo wa la ó dágbére lọ́jọ́ kan- Pásítọ̀ Odukoya
- Mi ò lè sùn, mó ń ronú, mi ò lè ṣe ǹkan torí Lanre - Princess
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ti araalu ba hu iwa ọdaran, o ti di dandan ki ijọba da sẹria fun irufẹ araalu bẹẹ.
O ni "Iwa ọdaran ko ni orukọ meji bi koṣe iwa ọdaran, ṣugbọn ijọba ko le maa wo awọn ọdaran niran lai da sẹria fun wọn labẹ ofin."
"Mi o le sọ ni pato pe a maa yanju ọrọ to wa nilẹ pẹlu ọrọ oṣelu, pẹlẹkutu tabi pe a o jeburẹ lai ṣe pe awọn ti ọrọ kan kọkọ kan si wa."
"Ti wọn ba kan si wa lori ọna abayọ, a oo gbe ohun ti wọn ba sọ yẹwo to ba ni gbongbo, to ba jẹ eyii to ni gbongbo lẹyin naa ni a le sọ boya ijiroro le waye."
Malami sọ pe ijọba ko kan le dede sọ pe ọna kan bayii tabi ọna miran ni awọn yoo gbe ọrọ naa gba.
O ni "a o kan le dede gbe igbesẹ ijiroro tabi ọna abayọ lọna oṣelu bayii lai ṣe pe awọn ti ọrọ kan kọkọ kan si wa, ṣugbọn a oo mọ ohun ti a o ṣe ti akoko ba to."
Ṣaaju ni Igboho ti kọkọ bọ mọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS lọwọ lasiko ti wọn kọlu ile rẹ loru ọganjọ ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun yii, niluu Ibadan.
Lẹyin naa lo tẹkọ leti lọ silẹ Benin Republic, lọna ati gba ibẹ lọ si Germany, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa agbaye, Interpol mu mọlẹ, to si gba ibẹ de ile ẹjọ Benin.
Ni ti Kanu, ijọba Naijiria fi tipa-tikuku ji gbe lati ilẹ Kenya wa si Naijiria lati jẹjọ lori ẹsun iditẹ ati igbiyanju lati da Naijiria ru.
















