Ikoyi house collapse: Wọ́n tún ti yọ òkú èèyàn méjì síi níbi ilé tó wó l'Eko, èèyàn mẹ́ẹ̀dógún ló mórí bọ́

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi pajawiri tun ti yọ eeyan labẹ ogiti alapa ile da wo lagbegbe Ikoyi niluu Eko ni Ọjọru.
Eyi lo jẹ ko di eeyan marunlelogoji to ku nibi iṣẹlẹ naa bayii lẹyin ti wọn ti yọ mẹtalelogoji tẹlẹ.
Kọmiṣọnna eto iroyin nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gbenga Omotoso lo fọrọ yii lede lalẹ Ọjọru loju Facebook ijọba ipinlẹ Eko.
- 'Ẹ yé tan ara yín, èmi mo ni aṣọ 120 yard tó jábọ́ lát'ọ̀run táwọn ará Ondo ń ya mọ́ ara wọn lọ́wọ́'
- 'Ẹni kọ̀ọ̀kan tó fẹ́ rà nínú ilé alájà 21 tó wó l'Eko ti ṣàdéhùn láti san N206m sí N1.24bn kó tó wó'
- Ta ló ni ilé alájá 21 tó wó pa àwọn èèyàn ní Ikoyi gan? Ìjọba Eko ti fèsì
- ''Mo ti gbàdúrà fún àànú láti r'ọ́run wọ̀ lẹ́yìn tí mo wà lábẹ́ ilé tó wó ní Ikoyi fún ọjọ́ kan''
- Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi
- 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'
- Taa ni arẹ̀wà obìnrin, Emmanuella Ropo tí ìròyìn n sọ pé òun ni ìyàwò K1 tuntun?
- Bí mo ṣe ká a sára tí mo gbé òkú ọmọ sínú ọkọ̀ lọ ṣe iṣẹ́ apanilẹ́rìín láì fihàn - Woli Agba Ayo Ajewole
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade fẹ́ ṣègbéyàwó lọ́tẹ̀ yìí lóòtọ́? Lateef bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀
Bakan naa ni o ṣalaye pe irọ ni ahesọ ọrọ kan tawọn eeyan n gbe kiri pe ijọba ti paṣẹ pe ki wọn wo awọn ile meji ti ileeṣẹ Fourscore Limited kọkọ kọ sẹgbẹ eyii to wo lulẹ.
Omotosho ni ''igbimọ to n ṣe iwadii lori iṣẹlẹ ile to wo ni Ikoyi ṣi n ba iṣẹ wọn lọ.
Igbimọ yii lo maa ṣe ayẹwo lori awọn ile meji ti wọn kọkọ kọ sẹgbẹ eleyii to wa lati mọ bo ya ijọba maa da a wo lulẹ.
Wọn ko tii ṣe ayẹwo yii, nitori naa o lodi fun awọn eeyan lati maa sọ pe ijọba ti ni ki wọn wo awọn ile naa.
Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ṣi n ba iṣẹ lọ nibi ile to wo, lilọ bibọ ọkọ lopona Gerrard ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ti n lọ geere lẹyin ti a ṣi ọna ọhun pada.
Awọn ẹbi ti awọn eeyan wọn wa lara awọn to ku nibi iṣẹlẹ naa ṣi n lọ si ile iwosan IDH ni Yaba lati gbe oku eeyan wọn.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Ẹbi to to mejilelọgbọn lo ti lọ fun ayẹwo ara wọn ni ile iwosan naa lati le mọ oku to jọ ti wọn.
Ti ayẹwo ko ba le fidi rẹ mulẹ daadaa, ijọba maa jọwọ oku naa fun ẹbi to fẹ gbe e.
Ijọba ti gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo maa ṣe amojuto bi wọn ṣe n gbe oku awọn eeyan fun ẹbi wọn.
Ọjọ kinni oṣu kọkanla yii ni ile alaja mọkanlelogun naa da wo lojiji ni opopona Gerrad ni Ikoyi nibi ti eeyan marunlelologoji ti ku ti eeyan mẹẹdogun ti mori bọ.
















