Doctor Joy Adesina: Kìí ṣe gbogbo ìgbà náà ni mo fi ń kàwé ní fásitì, ẹ gbé ìgbé ayé tó dọ́gbà láti tayọ
Laipẹ yii ni iroyin ọdọbinrin kan kan ka pe o tayọ gidi gidi ninu imọ ẹkọ dokita to si jẹ ẹbun ile ọfẹ, iṣẹ, owo tabua ati ọpọlọpọ ami idamọ fun oriire ni ile iwe Obafemi Awolowo ti Ile Ife ot ti jade.
Aworan rẹ tan ka ori ayelujara nigba ti aarẹ banki idagbasoke ilẹ Afirika, Akinwumi Adesina gbe aworan rẹ sori sori ayelujara, ẹgbọn lo jẹ si baba rẹ o si kọ ọrọ sita pe ori oun wu pe Joy lo tayọ ju pẹlu ami idayatọ mẹwaa atawọn ami ẹyẹ mii.
Dokita Joy Adesina ni akẹkọgboye ti yoo kọkọ gba iru awọn ami ẹyẹ yii ninu itan ile ẹkọ giga OAU to ti jade.
'Ẹ yé tan ara yín, èmi mo ni aṣọ 120 yard tó jábọ́ lát'ọ̀run táwọn ará Ondo ń ya mọ́ ara wọn lọ́wọ́'
Amọ iroyin arabinrin ko jina si iru ibẹrẹ to ni eyi to fihan pe iyi wa ninu ki obi máṣe gba fun ọmọ ni kekere lati maa fi ẹkọ rẹ ṣere rara.
"Lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni mo ti tẹpa mọ iwe mi, lati ọdun mẹsan ni mo ti kọkọ iwe ti awọn eeyan n ka".
Dokita Joy Adesina jẹ ọmọ aburo eekan agbaye to jẹ oludari patapata fun Banki idagbasoke ilẹ Afirika, Akinwumi Adesina, ọmọ iya ọmọ baba ni wọn.
Joy ni lati kekere naa ni oun ti maa n tayọ amọ nigba ti oun wọ ile iwe giga fasiti gan, ko kọkọ rọrun fun oun ni ipele ikini amọ nigba to de ipele keji to bẹrẹ si ni rii pe esi idanwo oun n dara lo ti rii pe oun naa yoo tayọ.
"Esi idanwo ti mo n ri lo n jẹ iwuri fun mi lo jẹ ki n de ibi ti mo de bayii".
Nigba to pari ni ipele aṣekagba ni okiki rẹ tan lori ayelujara to si gba ami itayọ (Distinction) mẹwaa, ami itayọ marun mii. Eyi lo mu ki awọn eekan lawuj bẹr si ni fi ẹbun yẹ ẹ si. Gomina Dapo Abiodu fun un ni ẹbun owo ati ile ọfẹ pe ohun iwuri gbaa ni esi rẹ jẹ.

