Woli Agba Ayo Ajewole: Mo bọ́ sínú ọkọ̀, mo kéé gidi gan mo sì nu ojú nù lọ ṣe eré lórí ìtàgé

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe káa sára tí mo gbé òkú ọmọ sínú ọkọ̀ lọ ṣe iṣẹ́ apanilẹ́rìín láì fihàn - Woli Agba Ayo Ajewole

Woli Agba: Ti wọn ba sọ fun mi pe iyawo mi ti bimọ mo fẹ lọ kede rẹ lori itage ere ti mo n ṣe lọwọ ki wọn ba mi yọ...

Dokita: Woli Agba a dẹ maa n gbadun yin gan o, koda mo gbiyanju gidi gan amọ ma binu o ọmọ taa n reti ti pada

Woli Agba: O pada, lọ sibo, o pada bawo, ki lo lọ ṣe?

"Dokita ni gẹgẹ bi iṣẹ mi, ki n tun lọ pa iyawo mi lẹrin lori bẹ́ẹ́dì ile iwosan lẹyin to sọ fun mi pe oun gbiyanju ṣugbọn mọ taa bi ti pada".

Gbajugbaja adẹrinpoṣonu ti ọpọ eniyan fẹran, Ayo Ajewole ti orukọ itage rẹ n jẹ Woli Agba kẹnu bọ ọrọ, omi kun rọrọ si ni loju bo ṣe n ṣalaye fun BBC Yoruba oun toju apanilẹrin n ri labẹ aṣọ amọ tẹrin tẹrin yii naa lo tun fi n sọọ.

Ninu akanṣe ifọrọwanilẹnuwo taa ṣe pẹlu rẹ, apanilẹrin yii ṣalaye bo ṣe ku fẹẹrẹ ko gun ori itage lọjọ kan to si gba ipe pe ko maa bọ nileewosan ti iyawo rẹ ti n rọbi lọwọ.

"Ni ọjọ ti mo ni iṣẹ apanilẹ́rin lati ṣe gangan ti awọn eeyan ti n reti pe Woli Agba n bọ o ni mo gba ipe lati ileewosan".

Ero Woli Agba ni ko de ileewosan ki wọn sọ fun un pe o ti bimọ ko lee pada sọọ lori itage pe ki wọn ba oun yọ ni wọn ba ni Dokita fẹ rii ni ọfiisi.

Íroyin ibanujẹ ni Woli Agba ba pada lọ sinu ọkọ amọ alaye pọ ninu fidio yii bi woli Agba ṣe kaa sara to ṣi tun lọ ṣere lori itage lọjọ kan naa.

Ayo Ajewole wa sọ bi ọrọ rẹ ṣe pada di ayọ.