Ondo Sky Cloth: Bóyá ó ní ogún kan tó pọ̀ tó fẹ́ ja ìdílé mi ní Ọlọ́run bá mi fi gbígbé aṣọ yẹn ṣe ìṣẹ́gun

Àkọlé fídíò, 'Ẹ yé tan ara yín, èmi mo ni aṣọ 100 yard tó jábọ́ lát'ọ̀run táwọn ará Ondo ń ya mọ́ ara wọn lọ́wọ́'

Nkan bii ọjọ melo kan sẹyin ni ariwo gba gbogbo ilu kan nipinlẹ Ondo kan nigba ti awọn araalu bẹrẹ si ni fa aṣọ funfun nla kan mọ ara wọn lọwọ ti wọn n ya a kutukutu plu igbagbọ pe lati ọrun ni ọlọrun ti juu kalẹ wa si aye.

BBC Yoruba boju wo ọrọ yii a si ṣe iwadii finifini lati mọ ohun to ṣẹlẹ gangan.

Agnes Fadoju

Iwadii wa ni ipinlẹ Ondo lo fihan pe ibi ti aṣọfunfun pupọ oni yaadi pupọ ti awọn eeyan n du mọ ara wọn lọwọ yii ni ile arabinrin kan to maa n fi oriṣiriṣi aṣọ ṣe gbọngan ayẹyẹ ni ọṣọ.

Arabinrin Agnes Fadoju ṣalaye pe ni ọjọ ti oun fọ aṣọ naa, oun saa si ẹyin ile idana wọn ti gbogbo ara ile wọn si jade lọ ibi iṣẹ oojọ wọn.

"Lọsan ni awọn eeyan bẹrẹ si ni pe mi lati bi mi pe ṣe mi o sa aṣọ iṣ mi sita tori aṣọ kan wa loju ofurufu to ti rin jina to n dru ba eeyan to n ṣe bii ejo".

Agnes ni oun da wọn lohun pe aṣọ ti oun sa jẹ aṣọ to pọ gidi gan ti atẹgun ko lee gbe lọ.

Afi to ibẹ to rii ti wọn n pin aṣọ naa mọ ara wọn lọwọ lootọ to si ri aridaju pe aṣọ oun ni.

Koda o ni ọpọ eeyan lo n taa mọ ori ti wọn n fi si ori ọja wọn pẹlu igbagbọ pe iyanu ni lati ọrun.

Ọkọ arabinrin naa, Akinolu Fedogun fi kun un pe iyawo ohun lo sa aṣọ to fi n ṣe iṣẹ ṣiṣe gbọngan ayẹyẹ lọṣọ̀ọ́ sita ile idana wọn lọjọ Iṣẹgun ọsẹ ti iṣẹlẹ náà ṣẹ.

Agnes