Wòlìí Israel Ogundipe Oladele Genesis Global tú àṣírí àwọn tó sọ̀rọ̀ rẹ̀ láburú lásìkò tó wà lẹ́wọ̀n

Wolii Genesis

Oríṣun àwòrán, Genesis Global

Ilumọọka Wolii to tun jẹ adari ijọ CCC Genesis Global Church, Isreal Ogundipe Oladele ti sọ iru irẹpọ to wa laarin rẹ ati gbajugbaja akọle to kagbako iku nibi ile alaja mọkanlelogun to wo ni Ikoyi, ipinlẹ Eko.

"Ko kan mi ohun ti awọn eeyan ba n sọ nipa emi o, bi mo ba wa ni isọkan pẹlu rẹ mo wa ni isọkan pẹlu rẹ naa niyẹn, mo gba gbogbo ẹyin ọmọ ijọ Genesis Global nimọran lati yẹra kuro ninu biba wọn gbe iroyin aburu kiri".

O ni ko ni fi ṣe iru iroyin kiroyin ti ẹnikẹni ba n gbe kaakiri, gbogbo eeyan ni yoo pari iroyin rẹ laye. Wolii Genesis ni eleyii gan n ṣẹlẹ ninu ijọ.

O ni awọn to parọ mọ nigba ti wọn fi oun si ahamọ ti wa n jẹwọ bayii ti lara wọn si ti n foju ba ile ẹjọ.

Wolii Genesis ṣalaye pe nipa oun gan to si n bi awọn ọmọ ijọ rẹ naa pe ṣebi awọn naa gba fidio ọhun lori foonu wọn ti wọn n fi han oun pe oun maa n ba iya to bi oun lọmọ sun ni gbogbo ọjọ Isegun lati gba agbara.

Àkọlé fídíò, Wo òkè ìṣẹ̀mbáyé Abanijorin yìí l'Ekiti tó máa ń bá ọ̀kọ̀ rìn lójú pópó tó tún ní ilé ìwòran orí ìtàgé nínú rẹ̀
Genesis

Oríṣun àwòrán, Genesis Global

"Wọn tilẹ tun sọ pe gbogbo awọn akọrin ijọ ni mo ti ba sun tan ti wọn si n gbe fọto wọn si ẹgbẹ temi to fi mọ awọn abilekọ to lọrọ ti Ọlọrun n lo lati fi ran mi lọwọ.

Koda wọn tun sọọ debi pe obinrin Ajinhinrere ti gbogbo agbaye mọ kan to jẹ iya ninu Oluwa fun mi n fẹ ki n ba oun lopọ, melo ni gbogbo ara mi gan, lai ṣe "machine gun".

Woli Genesi ni ọpọ duro lori eyi bi wọn ṣe ko ọpọ ọta jọ lodi si ohun wọn si yapa kuro lọdọ oun amọ Ọlọrun duro ti oun.

Àkọlé fídíò, Wo òkè ìṣẹ̀mbáyé Abanijorin yìí l'Ekiti tó máa ń bá ọ̀kọ̀ rìn lójú pópó tó tún ní ilé ìwòran orí ìtàgé nínú rẹ̀

Ki lo wa laarin Genesis ati oloogbe Femi Osibona?

Femi Osibona ati Woli Genesis

Oríṣun àwòrán, Genesi Global

Genesis tun wa sọ nipa iru irẹpọ to wa laarin rẹ ati gbajugbaja akọle to kagbako iku nibi ile alaja mọkanlelogun to wo ni Ikoyi, ipinlẹ Eko.

O ni Femi Osibona ko si laye bayii lati gbeja ara rẹ ki awọn eeyan jẹ ki ẹmi rẹ sinmi.

"Ọmọ ijọ Celestial ni Femi Osibona mo si ni ọpọlọpọ fidio rẹ lori foonu mi ti mo le fihan yin. Mo ti ri ọpọ ile to dawo nilẹ okere ti wọn ko si da bi ru ẹnikẹni, abajọ ti inu awọn Yoruba kii dun si iṣere ẹlomiran".

Wolii Genesis ni to ba ṣe talaka, awọn eeyan a boo mọlẹ amọ to ba ti jẹ ẹni ti Ọlọrun ṣe fun, o ti daran.

Àkọlé fídíò, Oluwo dá èsì ńlá padà fún àwọn olórìṣà tó ní kò tọ́ síi kó ní Ọba Yorùbá kìí ṣe ìgbákejì Òrìṣà

"Ẹ n sọ pe wọn o fi iyẹpẹ to daa abi simẹnti gidi kọ ile naa, ile baba yin ati baba nla baba yin labule ṣe simẹnti ni wọn fi kọọ ni? Iyẹpẹ lasan ti wọn fi kọọ gan ko wo ri, igba tẹ n mu omi amu to ni tanwiji ninu ẹ ko ranti. Tẹẹ ba ti wa ri ni to n gun mọto meji, ẹẹ bẹrẹ si ni o n gberaga, yin Yoruba ṣe wọn ṣepe fun yin ni, wọn fi iṣ ṣe yin ni?"

O ni awọn abanijẹ o ki n ṣe rere laye o si fi eyi ni oun yoo kọ wọn ni koko meje nipa awọn eeyan nla ati Wolii nla tori "ti ọwọ rẹ ba ti mọ, aburu ko le ṣe ẹ, ṣe ẹ ro pe mo bẹru ni?"

Ẹni to bẹru iku lẹ le maa dẹru ba, mo ti lọ ẹwọn mo ti de. Ṣe o mọ iye eeyan ti Femi n fun lowo, to n ṣaanu fun, gbogbo ilu Ikene ṣe lo kan gogo..."

"Femi Osibona sọ fun mi funrarẹ pe ile yẹn loun fẹ gbe, bawo ni yoo ṣe kọ ile ti yoo pa oun gan funrarẹ?" O ni bawo lẹ ro pe yoo ṣe ri lara baba to bi Femi Osibona ko maa gb lasiko ọfọ

O ni ka dupẹ lọwọ ijọba Eko ni to tete sare tete si didoola mi awọn to ku to ha sabẹ ile naa. Ati Woli Genesis ati gbogbo ọmọ ijọ lo dide duro fun idakẹrọrọ oniṣẹju kan lati ṣeranti ṣe ẹyẹ ikẹyin fun ọrẹ rẹ, arakunrin rẹ ati awokọṣe rẹ.

Wolii jẹ ko di mimọ bi onisowo naa ṣe ṣeleri miliọnu mẹẹdọgbọn fun ijọ rẹ lasiko ti o fi wa lahamọ ninu oṣu kọkanla ọdun to kọja.

Ninu fidio kan lasiko to ninu ijọ rẹ to fi si oju opo Facebook ijọ rẹ lo ti ṣalaye bi oniṣowo ọhun ṣe fun ijọ rẹ ni miliọnu marun un naira lọdun 2015 to si pada ṣeleri miliọnu mẹẹdọgbọn amọ ti ko pada fun wọn tori iku ti ṣagba rẹ.

O ṣapejuwe oloogbe Femi Osibona bii ọrẹ ati arakunrin rẹ ninu isin naa eyi to jẹ ọjọ kẹjọ ti o dagbere faye to si n ba gbogbo idile awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ kẹdun.

"Mi o ni dakẹ lati maa sọ eyi toripe gbogbo wa arinrinajo la jẹ laye, bi onikaluku ba de ibudokọ tirẹ, yoo bọọ lẹ".

Lori gbọyii-sọyii ti awọn eeyan n sọ nipa iru eeyan ti oloogbe Femi Osibona jẹ, Wolii Genesis ni "Femi Osibona ti emi mọ kii lo ọgbọn alumọkọrọyi.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe káa sára tí mo gbé òkú ọmọ sínú ọkọ̀ lọ ṣe iṣẹ́ apanilẹ́rìín láì fihàn - Woli Agba Ayo Ajewole

Lọdun 2015, Femi Osibona wa si ijọ wa o si tọwọ bọ iwe sọwedowo iye owo miliọnu marun fun wa, lasiko ti mo wa ni ahamọ Ọlọpaa, o wa o si ṣeleri miliọnu mẹdọgbọn fun wa ṣugbọn ko pada ṣẹlẹ laye".

Wolii naa ni ọna ti ko wọpọ ni Femi Osibona gba ku bẹẹ si ni ọna ti ko wọpọ ni oun yoo fi ṣeranti rẹ.

"Ọrẹ ni Femi Osibona jẹ si mi to si gbero lati gbe ninu ile naa funrarẹ. Ibẹ lo ti n ṣiṣẹ ni gbogbo igba amọ o ṣe ni laanu pe ọpọ eniyan lo ku nibi iṣẹlẹ naa".

O ni iṣẹlẹ aburu yii kii ṣe nipa Femi Osibona nikan amọ nipa gbogbo awọn to padanu ẹmi wọn nibi ile to wo naa.

O kẹnu bọ ọrọ nipa awọn to maa n gbe iroyin aburu kiri nipa eeyan "paapaa julọ awọn Yoruba, o ti too yin nipa iroyin irọ tẹ n gbe kiri pe awọn mọlẹbi Femi Osibona n ja ija gidi lori ogun to fi silẹ.

Ko si nkan to n jẹ bẹẹ rara rara. Mo ba aburo rẹ sọrọ laipẹ lori foonu. Mo jẹ ọkan lara awọn to n ṣakoso eto isinku rẹ. Mi o le layelaye ṣẹ́ Femi Osibona ggẹ bi ọrẹ mi ati arakunrin mi".

O ni baba to bi Femi ṣi wa laye, "ẹ lee woye iru imọlara ti wọn n ni ati ohun ti wọn n la kọja lọwọlọwọ".

Àkọlé fídíò, 'Òbí mi máa ń bá wa wí gidi ní kékeré, ohùn tí mo ṣe ní fásitì tó mú mi gba "Distinction" 10, àmi ẹ̀yẹ̀ 5, ilé ọ̀fẹ́, owó rèé'