Ibadan Petrol tanker accident: Tánkà agbépo bẹntíróò ṣubú n'Ibadan, àwọn èèyàn ń gbọ́n epo láì bẹ̀rù iná

Oríṣun àwòrán, Other
Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ilu Ibadan tii ṣe olu ilu ipinlẹ Oyo sọ pe tanka agbepo bẹntiro kan ti ṣubu lagbegbe Olorunsogo ti epo inu rẹ si danu.
Ohun to jẹ iyalẹnu ni pe wọn niṣe lawọn eeyan n gbọn epo to danu lai nan ni bo ya ina le gba lojiji.
Awọn to wa ladugbo naa fi idi rẹ mulẹ pe idaji Ọjọbọ oni ni tanka ọhun to gbe epo jala lọna ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn ṣubu ni Olorunsogo.
- Wọ́n tún ti yọ òkú èèyàn méjì síi níbi ilé tó wó l'Eko, ó ti di èèyàn 45 tó kú níbẹ̀ báyìí
- ''Mo ti gbàdúrà fún àànú láti r'ọ́run wọ̀ lẹ́yìn tí mo wà lábẹ́ ilé tó wó ní Ikoyi fún ọjọ́ kan''
- Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi
- 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'
- Taa ni arẹ̀wà obìnrin, Emmanuella Ropo tí ìròyìn n sọ pé òun ni ìyàwò K1 tuntun?
- Bí mo ṣe ká a sára tí mo gbé òkú ọmọ sínú ọkọ̀ lọ ṣe iṣẹ́ apanilẹ́rìín láì fihàn - Woli Agba Ayo Ajewole
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade fẹ́ ṣègbéyàwó lọ́tẹ̀ yìí lóòtọ́? Lateef bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀
A gbọ wi pe awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ti wa nibẹ ti wọn ṣi n sa apa wọn lati ri pe ijamba ina ko ṣẹlẹ lati ibẹ.
Ṣugbọn bi wọn ṣe kilọ fawọn eeyan lori ewu ijamba ina to le ṣẹlẹ, niṣe ni wọn kọ eti ikun tu wọn si bẹrẹ si ni gbọn epo.
Awọn eeyan agbegbe Olorunsogo ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe ọkọ tanka agbepo naa takati ti o si ṣubu soju ọna mọrosẹ Eko si Ibadan.








