Ikoyi house collapse: Bíríkìlà t'órí kó yọ ní òun rò pé òun máa kú ni lẹ́yìn tí ó wà lábẹ́ ògiri àlàpà fún ọjọ́ kan

Awọn oṣiṣẹ NEMA nibi ile to wo ni Ikoyi

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aja to re'le ẹkun to bọ, o yẹ ka ki aja ku ewu.

Bayii gan an ni ọrọ ṣe ri pẹlu awọn eeyan to moribọ nibi ile to da wo lagbegbe Ikoyi niluu Eko lọjọ kinni oṣu kọkanla.

Iroyin ko to amojuba ni ọrọ naa lẹyin tawọn ọhun ṣalaye ohun ti oju wọn ri labẹ ogiri alapa ti wọn ha si ki iranwọ to de lati fa wọn yọ.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe káa sára tí mo gbé òkú ọmọ sínú ọkọ̀ lọ ṣe iṣẹ́ apanilẹ́rìín láì fihàn - Woli Agba Ayo Ajewole
Àkọlé fídíò, 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'

Ọkan lara awọn eeyan mẹẹdogun ti ori ko yọ nibi iṣẹlẹ naa, Nurudeen Solagbade to ba awọn akọroyin sọrọ nile iwosan nibi to ti n gba itọju ṣalaye pe oun ko mọ pe oun ko ni ba iṣẹlẹ naa lọ.

Solagbade ẹni ọdun mẹtalelọgbọn wa lara awọn birikila to n rẹle nibi ile ọhun ki o to wo lulẹ.

Solagbade to jẹ ọmọbibi ilu Iwo ni awọn marunlelọgbọn ni awọn jọ lọ ṣiṣẹ nibi ile naa lati Ibafo nipinlẹ Ogun.

''Ori aja kẹẹdogun ile naa ni mo ti ṣiṣẹ nibi ti mo ti n rẹle ki ile naa to dawo lojiji lọjọ naa".

Ọjọ akọkọ ti maa lọ ṣiṣẹ nibẹ naa ni iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ, koda n ko ba ti lọ sibi iṣẹ ọhun amọ ko si owo ti mo fi le gbọ bukata ẹbi mi lọwọ ni.

Emi ati ọmọ ilu mi, Waliu Lateef ati Ayo(ti wọn si n wa oku rẹ) ni wọn gbe iṣẹ rirẹ aja kẹẹdogun naa fun pe awọn yoo san ẹgbẹrun lọna ogoji naira fun wa.

O kudiẹ ki a pari iṣẹ lọjọ naa ni ile yii dawo, mo kọkọ ro pe ẹrọ ''lift'' ile naa lo wo lulẹ ni ki n to rii pe ogiri alapa ti bo mi mọlẹ.

Lẹyin ti mo lo wa labẹ ogiri alapa fun ọjọ kan lai si ounjẹ, omi ati afẹfẹ lati mi sinu daadaa pẹlu oku awọn eeyan to rọgba yi mi ka, mo ro pe opin ti de ba aye mi ni.

Afi ti mo ri iho kekere kan ti aff ti rọra n fẹ wle gbe imu mi si.

Àkọlé fídíò, Wòólì Alfred kú lọ́dún 1964, ó tún padà wà sí ìlú Agelu f'ọ́jọ́ mẹ́rìnlá!

A o le sun o le sun loru ọjọ Aje iṣẹlẹ naa titi di owurọ ọjọ keji, a ni lati rakoro lọ si ibi iho kan ti atẹgun ti wọle diẹ diẹ lati le maa mi daadaa.

Laarẹ ọjọ keji ọjọ Iṣẹgun ni a gbọ ohun awọn eeyan ti a si bẹrẹ si ni ke fun iranwọ lati jade kuro labẹ ogiri to wo luwa mọlẹ.

Nigba to ya ni wọn da wa lohun pe ki a fara balẹ, Ọlọrun fun rẹ lo yọ wa, o ju ọgbọn ati oye wa lọ.

Mi o tiẹ lero wi pe mo le moribọ lati ri awọn ẹbi mi pada tori ọpọ ni a jọ ha si abẹ ile to da wo naa.

Mo si jẹ irora ni ẹyin ati ẹsẹ osi mi, ṣugbọn mo si n gba itọju to peye lọwọ nile iwosan,'' Solagbade lo sọ bẹẹ.

Ẹwẹ, Lateef to wa pẹlu Solagbade naa sọ pe oun ko mọ pe oun si tun le wa laye mọ.

Lateef ni ''mo ti gbadura lati beere fun aanu lọwọ Ọlọrun nitori mo ti ro pe opin ti de ba aye mi labẹ ile to wo lu wa mọlẹ.

Aanu Ọlọrun ko mi yọ tori mo ti gbadura ki n le ri ọrun wọ, ori idubulẹ ni mo wa fun ọpọ wakati ti o si rẹ mi sibẹ.

Ogiri ti wo lu ọpọ eeyan mọlẹ ti wọn si tiraka lati mi, kii ṣe iku to dara lati ku rara, koda n ko gbadura rẹ fun ọta mi.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Oku awọn eeyan pọ nibi ti mo wa eleyii to bami lẹru, n ko le ṣiṣẹ mọ nibi ile to ba ga pẹlu iriri mi nibi iṣẹlẹ yii.''

Lateef fi oju, aya ati ẹsẹ ọtun rẹ ṣeṣe, amọ o si n gba itọju lọwọ nile iwosan.

Gomina Babajide Sanwo-Olu fidi rẹ mulẹ pe eeyan mẹẹdogun ni Eledua ko yọ nibi iṣẹlẹ naa nigba ti wọn ti ri oku eeyan mejilelogoji yọ nibẹ.

Àkọlé fídíò, Protein Marasmus: Wo èwu tó wà nínú kí ọmọdé má ní èròjà Protein lára