Ikoyi building Collapse: Ó di dandan kí a wa iṣu dé ìṣàlẹ̀ kòkò l'órí ọ̀rọ̀ ilé tí ó wó ní Ikoyi-Tinubu

Ó di dandan ki a wá iṣu de ìṣàlẹ̀ kòkò l'órí ọ̀rọ̀ ilé tí o wó ni Ikoyi-Tinubu

Oríṣun àwòrán, officialbolatinubu

Gómínà ìpínlẹ̀ Eko nígbà kan rí tó tún jẹ́ aṣíwájú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Progress (APC) tí kí gómìnà Sanwo-Olu lẹyin láti ṣe iwádìí tó péye lórí ilé tó wó ni Ikoyi.

Tinubu ni ìjọba ìpínlẹ̀ Eko gbọ̀dọ sí gbogbo aṣọ lójú eégún ìṣẹ̀lẹ̀ náà kí ó sì rí dájú pé ó ṣe nǹkan tí ó tọ́ lórí ìdí tí ilé alájà méjìlélógún ṣe dàwó bẹ́ẹ̀ ní òpópónà Gerald ni Ikoyi.

"Ó hàn gbangba-gbàngbà pé nǹkan tó burú jáì ṣẹlẹ̀ níbi ilé náà, tí ó bá jẹ́ pé àwọn ènìyàn kan lo ṣe aṣemaṣe, ìyà tó tọ ni o yẹ kí wọ́n fi jẹ.

Ìdí ní pé, àwọn tó tí ṣòfò ẹ̀mí, àwọn tó farapa, àtí àwọn ẹbi waọ́n gbọdọ̀ rí ìdájọ́ ododo gbà bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, nǹkan tó jù bẹ́ẹ̀ lọ tọ sí wọn.

Tinubu wa bá àwọn ẹbi ti ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí kẹ́dùn fún àwọn ènìyàn wọn to papòdà, bẹ́ẹ̀ ló bẹnu atẹ́ lu bi ilé náà ṣe dàwó nínú àtẹjáde ti amúgbálẹ́gbẹ̀rẹ̀ fi ọwọ́ sí nílùú Abuja.

" Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ, ilé alájà mọ́kànlélógun tó dàwó ni ìlú Eko jẹ́ ohun tó banilákàn jẹ́ tí o sì duni gidi, a sì ti pàdánù ẹ̀mí, ìṣẹ̀lẹ̀ abúrú ńláńlá ni."

" Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tó n wá oúnjẹ òòjọ́ wọn láti tọ́jú ẹbí wọn lo wà níbẹ̀, ṣe ó wá yẹ ki wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọ́n lẹ́nu iṣẹ́?

Ko sí ẹni tí ó ta sí láti jẹ irú ìyà yìí, kò yẹ kí ẹbí kankan gbọ́ irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ nípa ènìyàn wan, ẹrù tó wúwo ni. " A gbàdúrà pé kí ọlọrun tẹ wọ́n si afẹ́fẹ́ rere, ó ṣe pàtàkì láti kàn si ẹbí wọn pẹ̀lú àdúrà ati ẹbu ìrànwọ́ nínú àsìkò yìí.

" Mó kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn tí ó fara pa, bákan náà ni ni mo gbóríyìn fún ìjọba ìpínlẹ̀ Eko, nítorí mo ms pé, yóò ṣètò ìtójú wọn àti gbogbo àwọn nàkan mííràn tí wọ́n nílò ni àsìkò yìí àti bi eewọn yóò ṣe padpa si ìgbéaye wọn tẹ́lẹ̀.