COP26: Àwọn olórí orílẹ̀èdè àgbáyé ṣèlérí dídẹ́kun gẹdú gígé nígbó lọ́dún 2030

Awọn olori orilẹede agbaye to le ni ọgọrun ni wọn ṣetan bayii lati dẹkun gige igi nigbo lọna kotọ.
Nigba ti a ba fi ri ọdun 2030, gẹgẹ bi ara awọn afẹnuko akọkọ to waye nibi ipade apero lori idaabobo oju ọjọ COP26 to n lọ lọwọ, ofin yii yoo ti wa si imusẹ.
Lara awọn orilẹede to wa ninu afẹnuko yii ni Brazil pẹlu ọpọlọpọ gbogbo saare igbo didi to ni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Omi inú ọ̀rá ní mo lọ rà, tí orí ṣe yọ mí níbi ilé tó dà wó - Ọlọ́pàá
- Àwọn agbébọn kọlu Fáṣítì ìlú Abuja, wọ́n jí èèyàn mẹ́fà gbé lọ
- Wòlíì kan fún òṣèré tíátà ní miliọnu mẹ́fà náírà láti fi tọ́jú àìsàn rẹ̀
- Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ dóju ìbò Anambra bolẹ̀ kan ìjàngbọ̀n - Ààrẹ Buhari
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ló mú kí ìjọba gbógun ti orísùn ọrọ̀ ajé mi - Yomi Fabiyi figbe ta
- EFCC gbé bàbá olówó Obi Cubana
- Fulani darandaran kò ṣe lè ní Kwara, wọ́n pọ̀ ju ọmọ onílùú lọ
- Èèyàn tó há sí abẹ́ ilé tó wó kò sí ẹni tó lè sọ ṣùgbọ́n òkú mẹ́rin là ri-Ọlópàá
- Ẹ bá mi bẹ ọkọ mi Aláàfin kó gbà mí padà, mo ti ṣe àṣìṣe - Olorì Damilola
Bakan naa ni aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari pẹlu ti fi ẹnu si ọrọ naa.
Ninu ọrọ tirẹ naa to sọ nibẹ, Aarẹ Buhari ni laipẹ ti oun ba de ipo gẹgẹ bi alaga agbarijọpọ orilẹede Afirika lori idaabobo igbo didi, ilẹ Africa yoo tubọ tun tẹmpẹlẹ mọ igbesẹ lati da awọn ilẹ to ti di aṣalẹ ni Afirika pada si ipo ọlọra.
Lara awọn ẹjẹ ti awọn olori orilẹede to peju nibi ipade COP26 naa jẹ ni akojọ biliọnu mẹrinla pọun ilẹ Gẹẹsi latọwọ awọn ijọba ati aladani fun igbesẹ tuntun ọhun.
Ọpọ awọn akọṣẹmọṣẹ lo ti kan sara si igbesẹ naa, amọṣa ohun to n kọ wọn lominu ni bi irufẹ ifẹnuko bẹẹ to waye lọdun 2014 ṣe kuna lati mu adinku ba wahala igi gẹdu gige ninu igbo lọna kotọ.
Olotu ijọba orilẹede Gẹẹsi, Boris Johnson to n gbalejo ipade naa nilu Glasgow ṣe apejuwe afẹnuko ọhun gẹgẹ bi "adehun to lamilaaka lati daabo bo awọn igbo lorilẹ aye.

Ipade naa yoo waye fun ọsẹ meji gbako, ọpọ si rii gẹgẹ bi ohun to ṣe pataki fun mimu iṣoro aṣemaṣe oju ọjọ ati ayika wa si iyanju.
Awọn orilẹede to ti fifẹ han fun afẹnuko naa ni:



















