Alaafin: Olorì Damilola ní òun ṣetán láti padà sí ààfin Oyo, ọ̀rẹ́ ló ní kí òun máa ba Aláàfin jẹ́

Oríṣun àwòrán, officialqueendamifanpage/Instagram
Yoruba ni bi obinrin ko ba dan ile ọkọ meji wo, ko ni mọ eyi to san.
Bẹẹ ni ọrọ Olori Damilola da bayii, ẹni tii se aya Alaafin Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta to ko kuro ninu aafin ni bii osu mẹfa sẹyin.
Damilola, tii se olori kekere lo n fi ẹsun kan Alaafin nigba naa pe oriade naa ko tọju oun ati ọmọ kansoso to bi fun.
- Nǹkán yan, wọ́n ń ṣe ìkówójọ fún Olorì Damilola láti fi gba ilé l‘Eko
- Olorì Damilola fi èpè ránṣẹ́ sí 'bàbá' rẹ̀ to ní kò padà sọ́dọ̀ Aláàfin
- Ṣé lóòtọ́ ni olorì méjì míì tún ti kúrò láàfin Oyo?
- Àwọn olorì Aláàfin fi oríkì awúnilórí yẹ́ ọkọ wọn sí fún àádọ́ta ọdún tó gorí ìtẹ́
- Eyí ni àwọn arẹwà 'ẹ̀lẹ̀ Daddy', àfẹ́fẹ́ tí Aláàfin fi ń mí
- Mo ti kúrò ní ààfin Oyo, kí ìròyìn tó ò jáde pé èmi àti Wasiu Ayinde n fẹ́ ara wa - Olori Badirat
- Bá wo ni òrékelẹ́wà Adedoja tó gbàmì ẹ̀yẹ ''Miss Oyo 2020'' ṣe jẹ́ sí Alaafin?
- Ṣé lóòtọ́ ni Alaafin Ọyọ ti fẹ́ olorì tuntun láti ẹ̀yà Igbo? Ẹ wo ǹkan tí a mọ̀ nípa rẹ̀
- Wò ó bí Alaafin àti aya àkọ́fẹ́ rẹ̀, Olorì Abibat ṣe pàdé ní èwe
Amọ iyalẹnu lo jẹ bayii pe Olori naa ti n ge ika jẹ, to si n kabamọ pe oun kuro ninu aafin Oyo.
Ninu ikede kan ti ayaba naa se soju opo Instagram rẹ lọjọ Aiku, lo ti ni oun wa tọrọ aforijin lọwọ gbogbo ẹbi Adeyemi, tii se Alaafin Oyo.
O ni awọn ohun ti oun sọ nipa Ọba naa kẹyin ni oun ti ko jẹ, ti oun si fẹ ki gbogbo ẹbi dari jin oun.
"Mo fẹ ko ye gbogbo eeyan pe kii se pe wọn kan nipa fun mi lati kọ nnkan ti mo n kọ yii, koda, ọkan ati ara mi lo ji pepe.
Mo si fẹ sọ pe gbogbo ohun ti mo ti sọ laidara nipa Alaafin, paapaa pe ọba alaye naa ko tọju mi ati idi ti mo fi kuro ninu aafin Oyo, lo jẹ irọ patapata.
Awọn ọrẹ mi lo ti mi pe ki n se bẹẹ, ko si wa lati ọkan mi."
Olori Damilola tun fikun pe oju oun ti la bayii, ti oun si ti mọ ọtun yatọ si osi, mo si kabamọ pe mo fẹ fi ori ade wọlẹ nita gbangba,
O fikun pe oun ti lọ sile Alaafin to wa nilu Eko ati Abuja lati lọ tuuba fun oriade naa, ti omije ti omije si ni oun fi n kọ ọrọ yii.
"Mo n bẹ gbogbo abiyamọ aye, ẹ ba mi bẹ ọkọ mi, Alaafin Oyo pe ko dari jin mi, mo ti se tan, o ti ja mi loju.

Oríṣun àwòrán, officialqueen_dami/Instagram
Gbogbo ẹyin ti mo si gba owo lọwọ yin, maa da owo yin pada ni kete ti mo ba tipada si ọdọ ọkọ mi ni aafin Oyo.
Oloye nikan ni ọrọ yii ye pe ko si ibi to dabi ile."
Bawo ni Olori Damilola se kuro ni aafin Oyo:
Ninu iroyin yii, Nigba to kuro ni aafin Oyo, olori naa ni ọrẹ oun kan ti oun ni ko maa ran oun lọwọ ninu asọ adirẹ ti oun n ta, to si n gbe ninu aafin pẹlu oun, ni Alaafin tun fẹ, to si ti loyun fun.
Amọ igba ti oun yari ni Ọba naa ni ki oun ko ẹru oun jade kuro ninu aafin, ti oun si gba Eko lọ.
Lasiko to wa ni Eko yii, ni Olori Damilola fi igbe ta pe oun ko ri owo ti oun yoo fi gba ile tabi tọju ara oun, ti awọn ẹlẹyinju aanu si bẹrẹ si da owo jọ fun.

Oríṣun àwòrán, Gistlovers
Bakan naa nio aburo baba to bi Olori Damilola ke sita nigba naa pe irọ ni gbogbo oun ti Olori naa sọ nitori Ọba Adeyemi n tọju rẹ.
Baba naa, to ni oun ni oun ku fun Damilola bii baba tun fikun pe Alaafin n tọju awọn aburo Damilola pẹlu, to si n sanwo ile ẹkọ wọn to fi mọ iya to bi Damilola gan alara.
Amọ se ni (ninu iroyin yii) Olori Damilola fesi pada fun baba naa nigba naa, to si ni onijẹkujẹ ni, ati pe o ti gba owo lọwọ Ọba Adeyemi lo se ni ki oun pada si aafin rẹ.

Oríṣun àwòrán, Damilola/instagram



















