Yomi Fabiyi: Kò bójú mu bí ẹgbẹ́ TAMPAN ṣe dá mí dúró torí sinimá Oko Iyabo, màá pe ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, realyomifabiyi/mrlatin1510/Instagram
Gbajumọ oserekùnrin, Yomi Fabiyi, ti ke si ẹgbẹ awọn oṣere, TAMPAN, lati pa orúkọ oun rẹ kuro ninu akọsilẹ awọn osere ti wọn fun niwe lọ rọọkun nile na tabi kuro ninu ẹgbẹ naa.
Fabiyi sọ pe oun kii ṣe ọmọ ẹgbẹ naa, nitori naa ni àṣẹ ti wọn pa ko ṣe le fidi mulẹ.
O ni oun ka lẹta kan ti wọn fi pe oun si ipade alaafia ninu oṣu Keje, sugbọn àṣírí pada tu si oun lọwọ pe nkan mii ni wọn fẹ sọ.
- Yomi Fabiyi ṣe fíìmù lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, Iyabo ló dá lé lórí
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ti dájọ́ fún Yomi Fabiyi àti igbákejì rẹ̀ lórí fíìmù Oko Iyabo
- Ìwà àbùkù tí kò bá ojú mu ni Yomi Fabiyi àti Dele Matti hù pẹ̀lú eré Ọkọ Iyabọ- TAMPAN
- Yomi Fabiyi, ìtíjú ńlá gbáà lo jẹ́ lórí fíímú ''Oko Iyabo'' tóo gbé jáde - Mercy Aigbe
- Yomi Fabiyi sọ̀rọ̀ sókè lóri bí TAMPAN ṣe gbé igi le lẹ́yìn
- Ẹni tí inú bá ń bí lórí fíìmù Oko Iyabo, le gba iléẹjọ́ lọ - Yomi Fabiyi
- Àwọn egungun ẹ̀yìn mi lágbo tíátà ní Adebimpe Oyebade fi ọ̀nà ẹ̀bùrú gbà mọ́ mi lọ́wọ́ - Yomi Fabiyi
- Toyin Abraham jọ̀wọ́ dáríjì mí - Yomi Fabiyi
- Iṣẹ́ tíátà tí bájẹ́, ẹni ẹlẹ́ni ló ń jẹ iṣẹ́ wa - Yomi Fabiyi
- Mo ti padà sí ẹ̀sìn òwúrọ̀ mi o! Ẹ̀ gbé Ọlọ́run tóbi - Yomi Fabiyi
Oṣu Keje ni ẹgbẹ TAMPAN fi ikede sita pe awọn da Yomi Fabiyi duro, ti wọn si ni ko lọ rọọkun nile na kuro ninu ẹgbẹ ọhun.
Igbesẹ yii waye nitori sinima Oko Iyabo ti Yomi Fabiyi gbé jade, eyi ti ọpọlọpọ tọka si pe o dá lori ẹjọ ẹsun ifipabanilopọ ti oserekunrin, Baba Ijesha n jẹ lọwọ.
Wọn ni o tako ofin ati ilana iṣẹ tiata lati lo orúkọ, akọsilẹ tabi iṣẹlẹ nipa ẹnikẹni, ninu sinima lai jẹ pe ẹni naa fi àṣẹ si i.
Yatọ si igbesẹ ẹgbẹ TAMPAN, ile ẹjọ tun pasẹ pe wọn ko gbọdọ safihan sinima naa ni ibikibi lasiko yii.
Ọgbẹni Fabiyi sọ pe ti ẹni ti kii ṣe akọṣẹmọṣẹ oṣere gan-an ba wo sinima Oko Iyabo, yoo ri pe oun ko si lara ẹni ti wọn fi ẹ̀tọ́ rẹ dùn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- EFCC gbé bàbá olówó Obi Cubana
- Fulani darandaran kò ṣe lè ní Kwara, wọ́n pọ̀ ju ọmọ onílùú lọ
- Bá wo ní ilé alájà 21 ṣe wó ní Ikòyí? Ẹ ṣèwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní kíákíá - Sanwo-Olu yarí
- Èèyàn tó há sí abẹ́ ilé tó wó kò sí ẹni tó lè sọ ṣùgbọ́n òkú mẹ́rin là ri-Ọlópàá
- Ẹ bá mi bẹ ọkọ mi Aláàfin kó gbà mí padà, mo ti ṣe àṣìṣe - Olorì Damilola
- Ìyà tó ń jẹ Ife lórí òpópónà tó bàjẹ́ kò tọ́, Buhari, Oyetola, ẹ wá nǹkan ṣe sí - Ooni
- Kí ló mú Lizzy Anjorin ṣe àyẹ̀wò DNA ọmọ rẹ̀?
- Ẹ wò àsọtẹlẹ tí Odumakin sọ nípa ìbejì tí ìyàwó rẹ̀ bí loṣù mẹ́fà tó jáde láyé
- Ọ̀pọ̀ ajìjàgbara Yorùbá Nation ló ń tan aráàlú jẹ láì sọ òtítọ́ - Seyi Makinde
O ni koda, gbogbo awọn ti wọn sọ pe oun fi sinima naa bá wi ni oun bọ̀wọ̀ fun pẹlu bi oun ko ṣe lo gbogbo orúkọ ti wọn n jẹ, aworan tabi ohùn wọn.
O ni "pẹlu nkan to ṣẹlẹ yii, ko buru ti mo ba sọ pe TAMPAN lo mu ki ijọba gbogun ti sinima mi, emi gan-an-gan, ati orisun ọrọ aje mi."
"Idi ni pe ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ni iṣẹ pari lori Oko Iyabo, saaju ki awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ to o pari iyansẹlodi wọn."
O ni ti akoko ba to, oun yoo fi ilana ofin gbèjà ara oun nitori pe oun ko bẹru eniyan kankan, a fi Ọlọ́run.

Oríṣun àwòrán, realyomifabiyi/Instagram
Lori ofin ti ile ẹjọ fi de sinima naa, Oko Iyabo, Ọgbẹni Fabiyi sọ pe oun yoo tẹle ofin naa bo se yẹ.
O sọ pe sinima oun kii ṣe nipa ẹjọ ifipabanilopọ ti Baba Ijesha n jẹ rara. " Nitori naa, gbigbogun ti sinima Oko Iyabo ko bojumu".



















