Obi Cubana: EFCC gbé bàbá olówó lórí ẹ̀sùn pé ó ń gbé owó púpọ̀ rìn, tí kò sì sanwó orí

Oríṣun àwòrán, obi_cubana/Instagram
Ilumọọka olowo kan ati olokoowo, Obinna Iyiegbu, ti ọpọ eeyan mọ si Obi Cubana lo ti kawọ pọnyin ro ẹjọ niwaju awọn osisẹ ajọ EFCC lọjọ Aje.
Ẹsun ti wọn fi kan ni pe o n gbe owo tuulu kiri, bakan naa ni wọn ni o tun n sa fun owo ori ni sisan.
Ọmọ bibi ipinlẹ Anambra naa to tun jẹ alakoso ile ijo kan lo gunlẹ si ileesẹ Ajọ EFCC ni Jabi, nilu Abuja ni deede aago mejila ọsan Ọjọ Aje.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ǹkan mẹ́ẹ̀dògún tó yẹ kí o mọ̀ nípa olówó ayé Obi Cubana
- Wàhálà ìjọba Nàìjíríà ló lé mi kúrò nílùú Abuja lọ Portharcourt tọ́rọ́ mi fi dayọ̀- Obi Cubana
- Èèyàn tó há sí abẹ́ ilé tó wó kò sí ẹni tó lè sọ ṣùgbọ́n òkú mẹ́rin là ri-Ọlópàá
- Ẹ bá mi bẹ ọkọ mi Aláàfin kó gbà mí padà, mo ti ṣe àṣìṣe - Olorì Damilola
- Ìyà tó ń jẹ Ife lórí òpópónà tó bàjẹ́ kò tọ́, Buhari, Oyetola, ẹ wá nǹkan ṣe sí - Ooni
- Kí ló mú Lizzy Anjorin ṣe àyẹ̀wò DNA ọmọ rẹ̀?
O si wa nibẹ nibi to ti n dahun ibeere tawọn osisẹ EFCC n takoto rẹ si titi di alẹ Ọjọ Aje.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹsun ti wọn fi kan baba olowo yalumọ naa ko fi bẹẹ rinlẹ, amọ ẹnikan sọ fawọn akọroyin pe gbigbe owo tuulu kiri ati aisan owo ori lawọn ẹsun ti wọn tii fi kan.
Bi o tilẹ jẹ pe ajọ EFCC ko tii jade sita wa salaye bi ọrọ naa se jẹ amọ iwadii ni lootọ ni Cubana wa ni akata EFCC.
Bẹẹ ba gbagbe, Obi Cubana yii ni ẹnu kun laipẹ yii lasiko to se isinku mama rẹ nilu Oba, nipinlẹ Anambra, to si na owo yawalu, ti aye gbọ, ti ọrun gan si mọ pẹlu.
O pa maalu to le ni igba, gẹgẹ bi iroyin ti sọ, ti ọpọ eeyan si n sọrọ nipa bi owo nla se wọlẹ sibi eto isinku naa nibi ti awọn eekanlu yika Naijiria ati loke okun peju si.



















