Lizzy Anjorin: Florida ọmọ mi gbà mi tórí kò mú ìdá kan nínú àbùdá mi, ti bàbá rẹ̀ ló mú

Oríṣun àwòrán, lizzyanjorin_original/Instagram
Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Lizzy Anjorin ti fi esi ayẹwo baba ọmọ rẹ to ṣe sita loju opo Instagram rẹ.
Lasiko to n kede esi ayẹwo ọhun, esi naa fi han pe ọkọ rẹ, ọgbẹni Lawal ni baba ọmọ naa.
Ninu atẹjade ọhun lo ti kede ọjọ ibi ọmọ naa bii ọjọ Kinni, ọsu Kọkanla, to si tun sọ pe ọmọ naa mu DNA baba rẹ, kaka ko mu ti oun.
Lẹyin naa lo ṣe fidio kan nibi to ti sọrọ lori ayẹwo naa ati esi to ba jade, o tun fi fidio ṣe ipolowo ọja to n ta.
- Ọkọ Lizzy Anjorin fí ẹ̀bùn ọkọ̀ N20m fi ta lọ́rẹ
- Ọlọ́run Ọba ti pa ẹ̀gàn mi rẹ́, a bímọ l'Amẹrika - Lizzy Anjorin
- Oògùn olóró cocaine ni Toyin Abraham fi ń sayé - Lizzy Anjorin
- Kò sí ọkùnrin tí yóò fún obìnrin tó halẹ̀ bíi tèmi lówó - Lizzy Anjorin
- Lizzy Anjorin sọ̀rọ̀ sókè lórí obìnrin tó ń ba fa sùrútù torí ọkọ rẹ̀
- Ìjà Toyin Abraham àti Lizzy Anjorin tún búrẹ́kẹ́
- Ọba alayé kan àti gómìnà kọ ẹnu ìfẹ́ sí mi, kí n tó fẹ́ Mr Lawal - Lizzy Anjorin
- Mo gbé ìgbésẹ̀ láti ṣẹ́ oyún ọmọ mi tuntun, ọkọ mi nàá sì faramọ́ nítorí pé...
- Toyin Abraham kìí bá èmi náà yọ̀, ni kò jẹ́ kí ń gbé e lárugẹ fún ayọ̀ ọmọ - Lizzy Anjorin
Ninu fidio naa ni Lizzy ti n salaye pe alaidaa ati alabosi ni ọpọ eeyan, ti wọn si ri ti oun ru oyun ọmọ oun, Florida fun osu mẹsan.
O ni oun ru kan egungun lasiko ti oun wa ninu oyun amọ oun ko mu ida kan ninu abuda ara ọun amọ o ko ida mọkandinlọgọrun ninu abuda baba rẹ.

Oríṣun àwòrán, lizzyanjorin_original/Instagram
Ṣaaju ni tọkọ-taya ọhun ti kọkọ ṣe suna ọmọ naa ni ilu mẹwaa nilẹ Amẹrika laarin oṣu Kẹfa ọdun yii.
Iyẹn lẹyin ti wọn ti kọkọ bi ọmọ naa loṣu Karun un.
Inu oṣu Keje ọdun 2020 ni tọkọ-taya naa ṣe igbeyawo nibi ti awọn mọlẹbi atawọn ọrẹ awọn mejeji peju si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ bá mi bẹ ọkọ mi Aláàfin kó gbà mí padà, mo ti ṣe àṣìṣe - Olorì Damilola
- Ọ̀pọ̀ ajìjàgbara Yorùbá Nation ló ń tan aráàlú jẹ láì sọ òtítọ́ - Seyi Makinde
- Ẹ wò àsọtẹlẹ tí Odumakin sọ nípa ìbejì tí ìyàwó rẹ̀ bí loṣù mẹ́fà tó jáde láyé
- Ohun tó gbé mi lọ sọ́dọ̀ Buhari lọ́jọ́ Àìkú rèé - Tinubu
- Ọwọ́ tẹ èèyàn mẹ́ta tó gbé òògùn olóró sínú ọṣẹ dúdú
- Agbébọn kọlu ṣọ́ọ́ṣì, èèyàn méjì kú, wọ́n kó ọ̀pọ̀ olùjọ́sìn lọ
- Wo ọ̀nà tí obìnrin tó ti ní ìbálòpọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣe le sọ ara rẹ̀ di ‘Virgin' lẹ́ẹ̀kejì
- Gómìnà díbọ́n bíi aláìsàn lọ ṣèwádí aṣemáṣe àwọn òṣìṣẹ́ iléèwòsàn, ọ̀rọ̀ kọ sísọ
- Ó ṣèèsì bọ́ sí wọ́n lọ́wọ́ ní, APC kò ṣetán láti ṣe àkóso ìjọba ní 2015 - Atiku
- Má ṣé wàhálà wàásù fún mi, mo ti yọ ìdájọ́ ọ̀run kúrò lọ́rọ̀ mi - Bobrisky
Ọpọ awọn ololufẹ Lizzy Anjorin lo ti bẹrẹ si n kii ku oriire lori ibi ọmọ naa.
Ẹwẹ, awọn eeyan kan lara awọn to n tẹle oṣere naa lori ayelujara sọ pe, ko bojumu to, bo ṣe fi esi ayẹwo naa sori ayelujara nitori ọjọ ọla ọmọ ọhun, nigba ti awọn miran fara mọ.

















