Tinubu: Ọ̀rọ̀ òṣèlú kọ́ ló gbé mi lọ sọ́dọ̀ Buhari, àbẹ̀wó lásán ni

Bola Tinubu ati Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, State House

Aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ti ṣe abẹwo si Aarẹ Muhammadu Buhari nile ijọba to wa l'Abuja.

Lẹyin ipade naa ni Tinubu sọ fun awọn akọroyin pe kii ṣe ọrọ oṣelu lo gbe oun lọ sọdọ Buhari.

Ni bayii ti eto idibo ọdun 2023 ti n sunmọle, ọpọ eeyan lo lero pe ọrọ oṣelu ni Tinubu lọ ba Buhari sọ.

Amọ nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin abẹwo naa, Tinubu sọ pe oun kan lọ ki Aarẹ kaabọ pada si Naijiria ni, iyẹn lẹyin to tajo de lati Saudi Arabia, nibi to ti lọ ṣe Umra.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agba oloṣelu naa ni oun lọ dupẹ lọwọ Buhari fun bo ṣe ṣabẹwo si oun niluu London lasiko ti oun lọ gba itọju nibẹ.

O ni "Abẹwo mi wa lati fi ẹmi imoore han si Aarẹ fun abẹwo to ṣe si mi lẹyin iṣẹ abẹ ti mo ṣe niluu London, eyii to mu inu mi dun gidi."

"Nitori naa idi ti mo ṣe lọ ki niyẹn, ati lati kii kaabọ lati Saudi."

Àkọlé fídíò, PDP Convention: Àrà ọ̀tọ̀ ní ìdìbò 'convention' tọ̀tẹ̀ yí, òru mọ́jú la ti yanjú

Tinubu tẹsiwaju pe "Kii ṣe nipa ọrọ oṣelu rara, mo kan lọ ki kaabọ ati lati dupẹ lọwọ rẹ fun ifẹ to fi han si mi ni, ko ju bẹẹ lọ."

Ti ẹ ko ba gbagbe, Aarẹ Buhari wa lara awọn ọgọọrọ oloṣelu to lọ sabẹwo si Tinubu lasiko to lọ gba itọju niluu London.

Ṣaaju naa ni ọpọ eeyan ti kọkọ ṣakiyesi pe awọn ko kofiri Tinubu laarin ilu fun saa kan, eyii to mu ki awọn kan maa sọ pe o ti jade laye ni.

Amọ agbenusọ rẹ yara tete ke sita ninu atẹjade kan pe irọ ni iroyin naa, koko lara ọta agba oloselu naa le.

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa