PDP 2021 Convention: Wo alága àtàwọn ọmọ igbìmọ̀ alákòsóo tuntun fún PDP tó wọlé níbi ìbò abẹ́nú

Oríṣun àwòrán, Other
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti yan Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin tẹlẹri, Sẹnetọ Iyorchia Ayuh gẹgẹ bi adari tuntun fun ẹgbẹ oṣelu naa.
Eyi jẹ ara igbaradi fun idibo gbogboogbo ti yoo waye ni ọdun 2023 ati ọna lati gba ijọba lọwọ ẹgbẹ APC to wa lori oye lọwọlọwọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Má ṣé wàhálà wàásù fún mi, mo ti yọ ìdájọ́ ọ̀run kúrò lọ́rọ̀ mi - Bobrisky
- Wo ọ̀nà tí obìnrin tó ti ní ìbálòpọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣe le sọ ara rẹ̀ di ‘Virgin' lẹ́ẹ̀kejì
- Kí ló mú ọkùnrin kan fi ejò Sèbé olóró pa aya rẹ̀ lójú oorun?
- Òjò owó àti ẹbùn ń rọ fún Iyabo Ojo fún ayẹyẹ ọdún kan ikú ìyà rẹ
- Ayẹyẹ ìwúyè Grand Mufti wáyé ní Iwo, ọ̀pọ̀ adarí ẹ̀sìn Islam péjú
- Agbébọn ṣe ń gba owò ilẹ̀ ní Ariwa, agbèrò ń gbà ní gúúsù, kò sí ìyàtọ̀ - Lai Muhammed
- Ìdìbò abẹ́nú APC Oyo pàpà wáyé lẹ́yìn tí jàǹdùkú mú alága ìbò abẹ́nú nígbèkùn
- Ìjíròrò tó wáyé láàrín Bola Tinubu àti Igbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo, ohun tí a rí gbọ́ nípa rẹ̀ nìyí
Apapọ awọn aṣoju yan Ṣẹnetọ Ayu lẹyin ti igbimọ ẹgbẹ gba lati sun ipo adari ẹgbẹ oṣelu si iha Ariwa orilẹede Naijiria.
Ohun ti a mọ nipa Senetọ Ayu;
- Agbegbe Gboko ni ipinlẹ Benue ni wọn ti bi Sẹnetọ Ayu,
- Olukọ ni ni ileẹkọ giga fasiti Jos ki o to darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu,
- Sẹnetọ Ayu ti kuro ti fi igba kan kuro ni ẹgbẹ oṣelu PDP lọ si ẹgbẹ oṣelu alatakọ nigba naa, Action Congress (AC),
- Ni Osu Keji, ọdun 2007 ni wọn fi panpẹ ọba mu Ayuh lori ẹsun igbesunmọmi, amọ ti wọn fi silẹ lẹyin ti wọn gba beeli rẹ,
- Ọdun 1992 si 1993 ni o fi wa ni ipo gẹgẹ bi Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin lorilẹede Naijiria lẹyin to ṣe ṣẹnẹtọ ni ẹgbẹ osẹlu Social Democratic Party, SDP,
- Ni Osu Kọkanla, ọdun naa ni wọn yọ ni ipo gẹgẹ bi aarẹ ile igbimọ aṣofin,
- Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, Ayuh ni baba iṣalẹ ni oṣelu fun gomina ipinlẹ Benue tẹlẹri ni ọdun 1999 si 2007, Geaorge Akume,
- Bakan naa ni Ayuh ṣiṣẹ fun ipolongo idibo aarẹ to gbe aarẹ Olusegun Obasanjo wọle ni ọdun 1999,
- Lẹyin igba naa lo di igbo minisita mu ni ijọba aarẹ tẹlẹri , Olusegun Obasanjo laaarin ọdun 1999 si 2007 gẹgẹ bi minisita fun ọrọ ileeṣẹ, ọrọ abẹle ati ọrọ agbegbe,
- Amọ Ayuh kuro ni ẹgbẹ oṣelu lo si AC lẹyin to ṣiṣẹ tako aarẹ Obasanjo lati dibo yan igbakeji aarẹ gẹgẹ bi aarẹ ni idibo to waye ni ọdun 2007,
- Lasiko ijọba ologun Sani Abacha ni Ayuh ṣiṣẹ gẹgẹ bi minista fun ọrọ ẹkọ.
Wayi o, awọn ọmọ igbimọ alakoso to to ogun niye ni wọn tun dibo yan lẹyin Iyorchia Ayu, tii se alaga wọn.
Lara awọn ipo ti wọn tun yan oloye si ni igbakeji alaga ni ẹkun ariwa ati guusu, akọwe, akapo, olori awọn obinrin ati ọdọ.

Oríṣun àwòrán, IYORCHIA AYU
Awọn ọmọ igbimọ alakoso tuntun fun ẹgbẹ oselu PDP ree:
Alaga apapọ ẹgbẹ PDP - Iyorchia Ayu
Igbakeji Alaga fun ẹkun Ariwa - Umar Damagum (Wọn dibo yan)
Igbakeji Alaga fun ẹkun Guusu - Taofeek Arapaja (Wọn dibo yan)
Akọwe apapọ ẹgbẹ - Samuel Anyanwu
Akapo ẹgbẹ - Ahmed Mohammed
Akọwe aato ẹgbẹ - Umar Bature
Akọwe isiro owo - Daniel Woyegikuro
Asaaju awọn obinrin - Professor Stella Effah-Attoe
Asaju igun ọdọ - Muhammed Suleiman
Amofin ẹgbẹ - Kamaldeen Ajibade
Akọwe alukoro ẹgbẹ - Debo Ologunagba
Oluyẹwe owo wo- Okechuckwu Daniel
Igbakeji akọwe ẹgbẹ - Setoji Kosheodo
Igbakeji Akapo ẹgbẹ - Ndubisi David
Igbakeji alukoro ẹgbẹ - Ibrahim Abdullahi
Igbakeji akọwe aato ẹgbẹ- Ighoyota Amori
Igbakeji akọwe owo - Adamu Kamale
Igbakeji asaaju awọn obinrin - Hajara Wanka
Igbakeji asaaju ọdọ - Timothy Osadolor
Igabkeji amofin ẹgbẹ - Okechukwu Osuoha
Igbakeji Oluyẹwewo - Abdulrahman Mohammed

Iyorchia Ayuh dí Alágá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, àwọn ọmọ ìgbimọ̀ tó kù rèé
Sẹnetọ Iyorchia Ayuh ti di alaga gbogboogbo tuntun fun ẹgbẹ oṣelu PDP lorilẹede Naijiria.

Eyi ni ọkan lara abajade esi idibo ti awọn aṣoju ẹgbẹ naa se, ti wọn si panupọ dibo fun gẹgẹ bi ẹni ti yoo dari wọn.
Ṣaaju ni alaga ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ, Uche Secondus lọ si ileẹjọ lati gbe igi dina ipade naa, amọ aayan rẹ yii jasi pabo.
Idibo naa waye ni Ọgbọnjọ, Osu Kẹwaa, ọdun 2021 ni gbagede Eagles Square ni olu-ilu orilẹede Naijiria, Abuja lati yan awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu naa.
Gomina ipinlẹ Adamawa, Ahmadu Fintiri to jẹ alaga igbimọ naa ni ipo mẹta pere ni wọn yoo dije fun ninu awọn ipo naa, lẹyin ti ẹnu ti ko lori awọn ti wọn yoo gbe si ipo yoku.
Gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọlagunsoye Oyinlọla ati igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Taofeek Arapaja ni wọn dije du ipo igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP fun ẹkun guusu Naijiria.
Bí àbájáde èsì ìdìbo abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣe lọ nì yìí:
Ki wọn to bẹrẹ si ni dibo ni awọn asaaju ẹgbẹ ti gbimọ pọ, ti wọn si yan adari ẹgbẹ naa, eleyii ti wọn pe ni ''Consensus Candidate''.
Ẹni akọkọ ti wọn kọkọ mu ni Alaga ẹgbẹ gbogboogbo ẹgbẹ PDP, Sẹnetọ Dr Iyorchia Ayu.
Umar Iliya Damagun ni wọn yan gẹgẹ bi igbakeji alaga ẹgbẹ fun iwọ Ariwa Naijiria.

Nigbati Taofeek Arapaja di igbakeji ẹgbẹ oṣelu PDP fun Guusu orilẹede Naijiria.
Ipo Akọwe ẹgbẹ lọ si iha ila oorun orilẹede Naijiria, iyẹn sẹnetọ Samuel Nnaemeka Anyanwu
Awọn esi idibo to ku re e;
Olori awọn ọdọ:
(1) Sulaiman Kadade
(2) El kudan
Igbakeji Alaga fun ẹkun Guusu:
(1) Taofeek Arapaja (Ipinle Oyo) ni ibo 2004
(2)Ọmọọba Olagunsoye Oyinlola (Ipinle Osun) ni ibo 705
Awọn Ibo ti ko wulo jẹ: 165
Igbakeji Alaga fun ẹkun Ariwa:
(1) Chiroma
(2)Damagun


















