PDP convention: Ìpàdé ìdìbò 'convention' ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń gbìnàyá l'Abuja

Aworan ibi ipade idibo ẹgbẹ oṣelu PDP nilu Abuja

Lẹyin ti igbesẹ alaga ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ, Uche Secondus lati pagidina igbade idibo itagbangba ẹgbẹ oṣelu PDP bọ si pabo, awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu naa yoo kọrajọ silu Abuja lọjọ Satide ọgbọnọjọ ati ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 2021 lati yan awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa.

Ṣaaju lọpọ ti n woye pe ṣe ipade idibo ẹgbẹ naa yoo lee waye lẹyin ti Uche Secondus gbe ẹgbẹoṣelu naa lọ siwaju ile ẹjọ kotẹmilọrun nibi ti ile ẹjọ kotẹmilọrun nilu PortHarcourt ti paṣẹ pe ko sohun to gbọdọ di ipade idibo naa lọwọ.

Aworan ibi ipade idibo ẹgbẹ oṣelu PDP nilu Abuja
Aworan ibi ipade idibo ẹgbẹ oṣelu PDP nilu Abuja

Ipo mọkanlelogun ni wọn yoo wa awọn eeyan tuntun ti yoo maa tukọ ẹgbẹ naa si, eeyan bii mẹtadinlọgbọn ni yo si maa du ipo naa.

Aworan ibi ipade idibo ẹgbẹ oṣelu PDP nilu Abuja

Amọṣa ohun ti Gomina ipinlẹ Adamawa, Ahmadu Fintiri to jẹ alaga igbimọ to n ṣe aayan ipade idibo gbogboogbo naa sọ ni pe ipo mẹta pere ninu awsn ipo naa ni wsn yoo dibo le lori lẹyin ti ẹnu ti ko lori awọn ti wọn yoo gbe si ipo yoku.

Aworan ibi ipade idibo ẹgbẹ oṣelu PDP nilu Abuja
Aworan ibi ipade idibo ẹgbẹ oṣelu PDP nilu Abuja

Itakangbọn fun ipo igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP fun ẹkun gusu Naijiria yoo wa laarin gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọlagunsoye Oyinlọla ati igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Taofeek Arapaja.

Aworan ibi ipade idibo ẹgbẹ oṣelu PDP nilu Abuja

O fidi rẹ mulẹ pẹlu pe igbimọ ayẹwo awọn oludije ti wọgile orukọ awọn oludije kan bii Wale Ọladipọ to gbero ati dije fun ipo igbakeji alaga, Eddie Ọlafẹsọ ati Akintan Oludaisi to gbero ati dije fun ipo akọwe ipolongo. Iwọgile wọn waye lori ẹsun pe wọn gbe ẹgbẹ oṣelu naa lọ sile ẹjọ lawọn asiko kan sẹyin.

Aworan ibi ipade idibo ẹgbẹ oṣelu PDP nilu Abuja

Bakan naa ni wọn tun wọgile erongba Amofin Muo-Aroh SAN lati dije fun ipo akọwe apapọ ẹgbẹ oṣelu naa nitori pe kii ṣe ipinlẹ Imo ti wọn pin ipo naa si lo ti wa.