Justice Mary Odili: Àwọn agbófinró ya bo ilé Onídájọ́ Mary Odili, àwọn ohun tuntun tó súyọ rèé

Oríṣun àwòrán, Other
Awọn agbofinro ya bo ile Onidajọ Mary Odili nilu Abuja lalẹ ọjọ Ẹti, eyi si ti n fa ọpọlọpọ ariwisi ati awuyewuye pẹlu bi o ṣe jẹ wi pe onidajs agba ni Mary odili ni ile ẹjọ to ga juls lorilẹede Naijiria.
Amọṣa, ajọ EFCC to jẹ ajs to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ ati gbogbo iwa aitọ miran to nii ṣe pẹlu iṣuna ati ọrọ aje lorilẹede Naijiria ni awsn ko mọ nipa rẹ o.
Bakan naa ni ileeṣẹ agbofinro DSS naa ti sọ pe laye o, awọn naa ko mọ nnkankan nipa rẹ.
Agbọn n sẹ ikandu nsẹ, oju oloko si ree gbagungbagun.
- A kò ní gbà kí Buhari yá $700m fi pèsè omi fún aráàlú - Ilé Aṣòfin
- Ọwọ́ ọlọ́pàá Ogun tẹ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó fẹ́ da ìdánwò rú
- Ilé ẹjọ́ ṣẹ́ eegun ẹ̀yìn Oluwo lórí yíyan Grand Mufti Yorùbá, àmọ́ Oluwo ní òun yóo fi oyè náà jẹ dandan
- Akọ̀ròyìn tó fi fọ́nrán ohùn Igboho síta ti wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Cotonou
- Uche Secondus tẹ́ lórí ọ̀rọ̀ PDP, adajọ́ ní ẹjọ́ rẹ̀ kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀
Ni alẹ ọjọ Ẹti kan naa ni Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike atawọn eekan to jẹ ọrẹ ẹbi Odili ti ṣabẹwo si ile naa lati ms bo ṣe n lọ nibẹ.
Koko ọrọ ni pe, lati awọn akoko diẹ sẹyin bayii, onidajọ Mary Odili ati ọkọ rẹ Peter Odili to figba kan ri jẹ gomina ipinlẹ Rivers ti n ni iforigbari pẹlu awọn alaṣẹ kan lorilẹede Naijiria, ko si si ẹni lee sọ ni pato ẹni gan ninu awọn mejeeji ti awọn agbofinro tori kọlu ile wọn.

Oríṣun àwòrán, other
Awọn iroyin abẹle kan n gbe kiri pe awọn agbofinro ni kikẹẹfin tawọn kẹẹfin pe "iwa aitọ" kan n lọ nile naa lawọn fi sare kọlu ibẹ lati lee koju rẹ.
ṣaaju asiko yii ni awọn iroyin kan ti jẹyọ lori ayelujara ninu eyi ti eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ Aliyu Ibrahim ti gbe jade ninu iwe ẹlẹri ofin kan pe awọn ọlọpaa n gbero lati gba iwe aṣẹ lati ls ṣayẹwo awọn ile kan nilu Abuja ti wọn fura si pe awọn iṣẹ to gba ifura ti n waye.

Oríṣun àwòrán, other
Lọjọ Ẹti ni adajọ Majisireeti agba kan ni ile ẹjọ majisireeti kan ni Wuse zone 6 nilu Abuja ti orukọ rẹ n jẹ Emmanuel Iyanna fun awsn agbofinro ni iwe aṣẹ naa, gẹgẹ bi BBC ṣe sewadi rẹ, sga slọpaa kan ti orukọ rẹ n jẹCSP Ajodo Lawrence lo si gba iwe aṣẹ naa.

Oríṣun àwòrán, other
Se lootọ ni adajọ Majisireeti agba Emmanuel Iyanna mọọmọ gbe aṣẹ kalẹ fun ikọlu agbofinro sile onidajọ Odili?
Nibayii adajọ Majisireeti agba Emmanuel Iyanna ti n sọ pe ileeṣẹ eto idajọ labẹ amofin agba orilẹede Naijiria, Abubakar Malami fi ọgbọn alumọkọrọyi tan oun ni lati gbe iwe aṣẹ ẹ lọ tu ile rẹ jade.
Awọn iwe iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria si ti gbee pe ni kete ti adajọ Majisireeti agba Emmanuel Iyanna ri oju ọrọ lo paṣẹ ki wọn wọgile iwe aṣẹ to kọkọ pa naa.
Gẹgẹ bi BBC ṣe rii ka, iwe aṣẹ naa wa fun ojule kẹsan, opopona Imo, Maitama Abuja, ṣugbọn adirẹsi ile Onidajọ Mary Odili tawọn agbofinro naa lọ kọlu jẹ ojule Kẹsan.

Oríṣun àwòrán, other

Oríṣun àwòrán, other

Oríṣun àwòrán, odili

Oríṣun àwòrán, other

Oríṣun àwòrán, other
Ki lawọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa sọ?
Awọn ọlọpaa ko tii sọ ohun tawọn oṣiṣẹ wọn n ṣe ni ẹnu ọna Onidajọ Mary Odili, bẹẹni ko daju boya Peter Odili wa nile lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Ohun ti a mọ ni pe ọga ọlọpaa CSP Ajodo Lawrence to gba iwe aṣẹ ile ẹjọ yii jẹ ọkan lara awọn ọmọ ikọ oluwadi labẹ igbimọ to n gba owo ori dukia labẹ ileeṣẹ eto idajọ lorilẹede Naijiria.
Ki ni Onidajọ Mary Odili sọ si ọrọ naa?
Agbẹjọro fun Odili ba awọn akọroyin sọrọ lẹnu ọna ile Onidajọ Odili.
O ṣe apejuwe iwe aṣẹ ile ẹjọ naa gẹgẹ bii "aṣiṣe ti ko yẹ ko waye"
Ohun ti BBC ri daju ni pe, ni nnkan bii agogo marun un irọlẹ lawọn agbofinro naa ya bo ile onidajọ Mary Odili, ṣugbọn awọn ikọ agbofinro to n ṣọ ile naa ko jẹ ki wọn ri aye wọle.
Igba akọkọ kọ niyi tawọn agbofinro yoo maa ya wọle awọn onidajọ lorilẹede Naijiria.














