Buhari Water Loan: Ilé aṣòfin ní òun ti fòǹtẹ̀ lu owóyàá ìpèsè omi fún ìgbà mẹ́ta láì sí ìyípadà

Omi mimu

Oríṣun àwòrán, Unicef

Erongba Aarẹ Muhammadu Buhari lati ya ẹẹdẹgbẹrin miliọnu Dọla fun ipese omi, ti ba ijakulẹ pade niwaju Igbimọ Ile Aṣofin to n ṣagbeyẹwo gbese ti Naijiria .

Saaju ni Buhari ti kọwe si awọn aṣofin pe ki wọn o buwọlu ki oun ya owo naa, ki ijọba rẹ le ni anfaani lati pese omi fun awọn ọmọ Naijiria ni igboro ati igberiko lọdun 2022.

Eto naa ni wọn pe ni ''Sustainable Urban and Rural Water Supply, Sanitation and Hygiene (SURWASH),'' labẹ idari ileeṣẹ to n mojuto alumọni inu omi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi awọn aṣofin ṣe kọ ẹbẹ yii waye lẹyin wakati mẹrinlelogun ti awọn aṣofin kọ erongba ijọba lati yá igba miliọnu Dọla fi ra nẹẹti to n pa ẹfọn.

Ninu aba isuna ọdun 2022 ti Buhari gbe lọ sile aṣofin ni wọn kọ eyi si.

Àkọlé fídíò, Kiki Osinbajo: T;o bá yá owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, máa gbìyànjú láti da padà

Awọn ọmọ igbimọ naa sọ pe ko bojumu lati tun ya owo lasiko ti Naijiria ni ọpọlọpọ gbese to n san lọwọ.

Alaga igbimọ naa, Sẹnetọ Clifford Ordia sọ pe igba mẹta ọtọọtọ ni wọn ti buwọlu owo yiya fun ipese omi.

Ordia sọ pe gbese ọtalenirinwo din mẹwa miliọnu Dọla kan wa nilẹ, bakan naa tun ni miliọnu mẹfa Dọla miran, ti wọn gba lọwọ Banki idagbasoke ilẹ Africa.

Wọn ni ileeṣẹ ijọba to n mojuto alumọni inu omi gbọdọ ṣalaye nkan to fẹ ẹ fi ẹẹdẹgbẹrin miliọnu Dọla ṣe fun ipese omi.

Ọkan lara awọn aṣofin naa, Obinna Ogba sọ pe awọn ọmọ Naijiria ko gbadun omi laduru owo ti wọn ti ya tẹlẹ.

Awọn ọmọ igbimọ naa fẹnuko lati ranṣẹ pe minisita fun ileeṣẹ ijọba naa, Adamu Suleiman pe ko wa a ṣalaye nkan ti wọn fi awọn owo ti wọn ya tẹlẹ ṣe.

Àkọlé fídíò, Oyo Jailbreak: Wo ọṣẹ́ tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n Abolongo ṣe fáwọn ará Oyo àti bí wọn ṣe rí wọn mú